2 Kí ni anfaani agbára wọn fún mi,àwọn tí wọn kò lókun ninu?
3 Ninu ìyà ati ebi,wọ́n ń jẹ gbòǹgbò igi gbígbẹ káàkiri lálẹ́ ninu aṣálẹ̀.
4 Ewé igi inú igbó ni wọ́n ń já jẹ,àní, àwọn igi ọwọ̀ tí kò ládùn kankan.
5 Wọ́n lé wọn jáde láàrin àwọn eniyan,wọ́n ń hó lé wọn lórí bí olè.
6 Wọ́n níláti máa gbé ojú àgbàrá,ninu ihò ilẹ̀, ati ihò àpáta.
7 Wọ́n ń dún bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ninu igbó,wọ́n ń kó ara wọn jọ sí abẹ́ igi ẹlẹ́gùn-ún.
8 Àwọn aláìlóye ọmọ,àwọn ọmọ eniyan lásán,àwọn tí a ti nà kúrò lórí ilẹ̀ náà.