20 “Mo ké pè ọ́, Ọlọrun, O kò dáhùn,mo dìde dúró, mo gbadura, o kò kà mí sí.
21 O dojú ibinu kọ mí,o fi agbára rẹ bá mi jà.
22 O sọ mí sókè ninu afẹ́fẹ́,ò ń bì mí síhìn-ín sọ́hùn-únláàrin ariwo ìjì líle.
23 Dájúdájú mo mọ̀ pé o óo gbé mi lọ sí ipò òkú,ilé tí o yàn fún gbogbo eniyan.
24 Bí ẹni tí a ti là mọ́lẹ̀, tí kò lè dìde, bá ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ninu ìnira,dájúdájú o kò tún ní gbé ìjà kò ó?
25 Ṣebí mo ti sọkún nítorí àwọn tí wọ́n wà ninu ìṣòro rí,tí mo sì káàánú àwọn aláìní.
26 Ṣugbọn nígbà tí mo bá ń retí ohun rere,ibi ní ń bá mi.Nígbà tí mo bá sì ń retí ìmọ́lẹ̀,òkùnkùn ni mò ń rí.