25 Ṣebí mo ti sọkún nítorí àwọn tí wọ́n wà ninu ìṣòro rí,tí mo sì káàánú àwọn aláìní.
26 Ṣugbọn nígbà tí mo bá ń retí ohun rere,ibi ní ń bá mi.Nígbà tí mo bá sì ń retí ìmọ́lẹ̀,òkùnkùn ni mò ń rí.
27 Ọkàn mi dàrú, ara mi kò balẹ̀,ọjọ́ ìpọ́njú dé bá mi.
28 Mo fa ojú ro, mò ń káàkiri,mo dìde nàró láti bèèrè ìrànlọ́wọ́ láàrin àwùjọ.
29 Mò ń kígbe arò bí ajáko,mo di ẹgbẹ́ ẹyẹ ògòǹgò.
30 Àwọ̀ ara mi di dúdú, ó ń bó,egungun mi gbóná fún ooru.
31 Ọ̀fọ̀ dípò orin ayọ̀ fún mi,ẹkún sì dípò ohùn fèrè.