4 Ewé igi inú igbó ni wọ́n ń já jẹ,àní, àwọn igi ọwọ̀ tí kò ládùn kankan.
5 Wọ́n lé wọn jáde láàrin àwọn eniyan,wọ́n ń hó lé wọn lórí bí olè.
6 Wọ́n níláti máa gbé ojú àgbàrá,ninu ihò ilẹ̀, ati ihò àpáta.
7 Wọ́n ń dún bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ninu igbó,wọ́n ń kó ara wọn jọ sí abẹ́ igi ẹlẹ́gùn-ún.
8 Àwọn aláìlóye ọmọ,àwọn ọmọ eniyan lásán,àwọn tí a ti nà kúrò lórí ilẹ̀ náà.
9 “Nisinsinyii mo ti di orin lẹ́nu wọn,mo ti di àmúpòwe.
10 Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn,wọ́n ń rí mi sá,ara kò tì wọ́n láti tutọ́ sí mi lójú.