10 Sibẹ Ọlọrun wá ẹ̀sùn sí ọ lẹ́sẹ̀,ó sọ ọ́ di ọ̀tá rẹ̀,
11 ó kan ààbà mọ́ ọ lẹ́sẹ̀,ó sì ń ṣọ́ ìrìn rẹ.
12 “Jobu, n óo dá ọ lóhùn,nítorí pé bí o ti wí yìí, bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí.Ọlọrun ju eniyan lọ.
13 Kí ló dé tí ò ń fi ẹ̀sùn kàn ánpé kò ní fèsì kankan sí ọ̀rọ̀ rẹ?
14 Nítorí Ọlọrun sọ̀rọ̀ bákan, ó tún tún un sọ bámìíràn,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yé.
15 Ninu àlá, lójú ìran ní ààrin òru,nígbà tí eniyan bá sun oorun àsùnwọra, lórí ibùsùn wọn,
16 Ọlọrun a máa ṣí wọn létí,a máa kìlọ̀ fún wọn, a sì máa dẹ́rùbà wọ́n,