14 Nítorí Ọlọrun sọ̀rọ̀ bákan, ó tún tún un sọ bámìíràn,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yé.
15 Ninu àlá, lójú ìran ní ààrin òru,nígbà tí eniyan bá sun oorun àsùnwọra, lórí ibùsùn wọn,
16 Ọlọrun a máa ṣí wọn létí,a máa kìlọ̀ fún wọn, a sì máa dẹ́rùbà wọ́n,
17 kí ó lè dá wọn lẹ́kun ìṣe wọn,kí ó lè gba ìgbéraga lọ́wọ́ wọn;
18 kí ó lè yọ ọkàn eniyan kúrò ninu ọ̀fìn ìparun,kí ó má baà kú ikú idà.
19 “OLUWA a máa fi ìrora jẹ eniyan níyà lórí ibùsùn rẹ̀;a sì máa kó ìnira bá egungun rẹ̀.
20 Tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu rẹ̀ yóo kọ oúnjẹ,oúnjẹ àdídùn óo sì rùn sí i.