2 Wò ó! Mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀,ọ̀rọ̀ sì pọ̀ tí mo fẹ́ sọ.
3 Òtítọ́ inú ni mo fi fẹ́ sọ̀rọ̀,ohun tí mo mọ̀ pé òdodo ni ni mo sì fẹ́ sọ.
4 Ẹ̀mí Ọlọrun ni ó dá mi,èémí Olodumare ni ó sì fún mi ní ìyè.
5 “Bí o bá lè dá mi lóhùn, dáhùn.Ro ohun tí o fẹ́ sọ dáradára,kí o sì múra láti wí àwíjàre.
6 Wò ó, bákan náà ni èmi pẹlu rẹ rí lójú Ọlọrun,amọ̀ ni a fi mọ èmi náà.
7 Má jẹ́ kí ẹ̀rù mi bà ọ́,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní le kankan mọ́ ọ.
8 “Lóòótọ́, o ti sọ̀rọ̀ ní etígbọ̀ọ́ mi,mo sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.