20 Tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu rẹ̀ yóo kọ oúnjẹ,oúnjẹ àdídùn óo sì rùn sí i.
21 Eniyan á rù hangangan,wọn a sì fẹ́rẹ̀ lè máa ka egungun rẹ̀.
22 Ọkàn rẹ̀ á súnmọ́ ibojì,ẹ̀mí rẹ̀ a sì súnmọ́ àwọn iranṣẹ ikú.
23 Bí angẹli kan bá wà pẹlu rẹ̀,tí ó wà fún un bí onídùúró,àní, ọ̀kan láàrin ẹgbẹrun,tí yóo sọ ohun tí ó tọ́ fún un,
24 tí yóo ṣàánú rẹ̀, tí yóo sì wí pé,‘Ẹ gbà á sílẹ̀, ẹ má jẹ́ kí ó lọ sinu ibojì,mo ti rí ìràpadà kan dípò rẹ̀.’
25 Jẹ́ kí àwọ̀ rẹ̀ jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde,kí agbára rẹ̀ sì pada dàbí ti ìgbà ọ̀dọ́;
26 nígbà náà eniyan óo gbadura sí Ọlọrun,Ọlọrun óo sì gbọ́ adura rẹ̀.Eniyan óo wá fi ayọ̀ wá siwaju Ọlọrun,yóo sì ròyìn ìgbàlà Ọlọrun fún gbogbo aráyé