6 Wò ó, bákan náà ni èmi pẹlu rẹ rí lójú Ọlọrun,amọ̀ ni a fi mọ èmi náà.
7 Má jẹ́ kí ẹ̀rù mi bà ọ́,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní le kankan mọ́ ọ.
8 “Lóòótọ́, o ti sọ̀rọ̀ ní etígbọ̀ọ́ mi,mo sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.
9 O ní o mọ́, o kò ní ẹ̀ṣẹ̀,ara rẹ mọ́ o kò sì ṣe àìdára kankan.
10 Sibẹ Ọlọrun wá ẹ̀sùn sí ọ lẹ́sẹ̀,ó sọ ọ́ di ọ̀tá rẹ̀,
11 ó kan ààbà mọ́ ọ lẹ́sẹ̀,ó sì ń ṣọ́ ìrìn rẹ.
12 “Jobu, n óo dá ọ lóhùn,nítorí pé bí o ti wí yìí, bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí.Ọlọrun ju eniyan lọ.