10 Yìnyín ti inú èémí Ọlọrun wá,gbogbo omi inú odò sì dì.
11 Ó fi omi kún inú ìkùukùu,ìkùukùu sì fọ́n mànàmáná rẹ̀ ká.
12 Wọ́n ń yípo lábẹ́ ìtọ́ni rẹ̀,láti mú gbogbo àṣẹ tí ó pa ṣẹ, lórí ilẹ̀ alààyè.
13 Ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀,bóyá fún àtúnṣe ni, tabi nítorí ilẹ̀ rẹ̀,tabi láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
14 “Fetí sílẹ̀, ìwọ Jobu,dúró kí o sì ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun.
15 Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọrun ṣe pàṣẹ,tí ó sì mú kí mànàmáná awọsanma tàn?
16 Ǹjẹ́ o mọ̀ bí ó ṣe so awọsanma rọ̀,iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ ni;