21 “Ẹnikẹ́ni kò lè wo ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀runnígbà tí ó bá ń tàn ní awọsanma,nígbà tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ tí ó sì gbá wọn lọ.
22 Láti ìhà àríwá ni Ọlọrun ti yọ,ó fi ọlá ńlá, tí ó bani lẹ́rù, bora bí aṣọ.
23 Àwámárìídìí ni Olodumare–agbára ati ìdájọ́ òtítọ́ rẹ̀ pọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kì í kọ òdodo sílẹ̀.
24 Nítorí náà, gbogbo eniyan bẹ̀rù rẹ̀,kò sì náání àwọn tí wọ́n gbọ́n lójú ara wọn.”