4 Lẹ́yìn náà, a gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,ó sọ̀rọ̀ ninu ọlá ńlá rẹ̀,bí ìgbà tí ààrá bá sán,sibẹsibẹ kò dá mànàmáná dúróbí àwọn eniyan ti ń gbóhùn rẹ̀.
5 Ohùn Ọlọrun dún bí ààrá tìyanu-tìyanu,a kò lè rí ìdí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
6 Ó pàṣẹ pé kí yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀,bẹ́ẹ̀ náà ni òjò wẹliwẹli,ati ọ̀wààrà òjò.
7 Ó ká gbogbo eniyan lọ́wọ́ iṣẹ́ kò,kí wọ́n lè mọ iṣẹ́ rẹ̀.
8 Àwọn ẹranko wọ ihò wọn lọ,wọ́n dákẹ́ sibẹ, wọ́n sá pamọ́.
9 Ìjì líle fẹ́ jáde láti inú yàrá rẹ̀,òtútù sì mú wá láti inú afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́.
10 Yìnyín ti inú èémí Ọlọrun wá,gbogbo omi inú odò sì dì.