6 Ó pàṣẹ pé kí yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀,bẹ́ẹ̀ náà ni òjò wẹliwẹli,ati ọ̀wààrà òjò.
7 Ó ká gbogbo eniyan lọ́wọ́ iṣẹ́ kò,kí wọ́n lè mọ iṣẹ́ rẹ̀.
8 Àwọn ẹranko wọ ihò wọn lọ,wọ́n dákẹ́ sibẹ, wọ́n sá pamọ́.
9 Ìjì líle fẹ́ jáde láti inú yàrá rẹ̀,òtútù sì mú wá láti inú afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́.
10 Yìnyín ti inú èémí Ọlọrun wá,gbogbo omi inú odò sì dì.
11 Ó fi omi kún inú ìkùukùu,ìkùukùu sì fọ́n mànàmáná rẹ̀ ká.
12 Wọ́n ń yípo lábẹ́ ìtọ́ni rẹ̀,láti mú gbogbo àṣẹ tí ó pa ṣẹ, lórí ilẹ̀ alààyè.