1 OLUWA tún sọ fún Jobu pé,
2 “Ṣé ẹni tí ń bá eniyan rojọ́ lè bá Olodumare rojọ́?Kí ẹni tí ń bá Ọlọrun jiyàn dáhùn.”
3 Nígbà náà ni Jobu dá OLUWA lóhùn, ó ní:
4 “OLUWA, kí ni mo jámọ́,tí n óo fi dá ọ lóhùn?Nítorí náà, mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
5 Mo ti sọ̀rọ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,n kò sì ní sọ̀rọ̀ mọ́.”