11 Fi ibinu rẹ hàn, wo gbogbo àwọn agbéraga,kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
12 Wo gbogbo àwọn agbéraga, kí o sì sọ wọ́n di yẹpẹrẹ,rún àwọn ẹni ibi mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
13 Bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ papọ̀,dì wọ́n ní ìgbèkùn sí ipò òkú.
14 Nígbà náà ni n óo gbà pé,agbára rẹ lè fún ọ ní ìṣẹ́gun.
15 “Wo Behemoti, ẹran ńlá inú omi,tí mo dá gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ọ,koríko ni ó ń jẹ bíi mààlúù!
16 Wò ó bí ó ti lágbára tó!Ati irú okun tí awọ inú rẹ̀ ní.
17 Ìrù rẹ̀ dúró ṣánṣán bí igi kedari,gbogbo iṣan itan rẹ̀ dì pọ̀.