13 Bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ papọ̀,dì wọ́n ní ìgbèkùn sí ipò òkú.
14 Nígbà náà ni n óo gbà pé,agbára rẹ lè fún ọ ní ìṣẹ́gun.
15 “Wo Behemoti, ẹran ńlá inú omi,tí mo dá gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ọ,koríko ni ó ń jẹ bíi mààlúù!
16 Wò ó bí ó ti lágbára tó!Ati irú okun tí awọ inú rẹ̀ ní.
17 Ìrù rẹ̀ dúró ṣánṣán bí igi kedari,gbogbo iṣan itan rẹ̀ dì pọ̀.
18 Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá idẹ,ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí irin.
19 “Ó wà lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí èmi Ọlọrun dá,sibẹ ẹlẹ́dàá rẹ̀ nìkan ló lè pa á.