15 “Wo Behemoti, ẹran ńlá inú omi,tí mo dá gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ọ,koríko ni ó ń jẹ bíi mààlúù!
16 Wò ó bí ó ti lágbára tó!Ati irú okun tí awọ inú rẹ̀ ní.
17 Ìrù rẹ̀ dúró ṣánṣán bí igi kedari,gbogbo iṣan itan rẹ̀ dì pọ̀.
18 Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá idẹ,ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí irin.
19 “Ó wà lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí èmi Ọlọrun dá,sibẹ ẹlẹ́dàá rẹ̀ nìkan ló lè pa á.
20 Orí àwọn òkè ni ó ti ń rí oúnjẹ jẹ,níbi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti ń ṣeré.
21 Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lotusi,lábẹ́ ọ̀pá ìyè ninu ẹrẹ̀.