3 Nígbà náà ni Jobu dá OLUWA lóhùn, ó ní:
4 “OLUWA, kí ni mo jámọ́,tí n óo fi dá ọ lóhùn?Nítorí náà, mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
5 Mo ti sọ̀rọ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,n kò sì ní sọ̀rọ̀ mọ́.”
6 Nígbà náà ni OLUWA tún bá Jobu sọ̀rọ̀ láti inú ìjì líle, ó ní,
7 “Múra gírí bí ọkunrin,mo ní ìbéèrè láti bi ọ́, o óo sì dá mi lóhùn.
8 Ṣé o fẹ́ sọ pé mò ń ṣe àìdára ni?O fẹ́ dá mi lẹ́bi kí á lè dá ọ láre?
9 Ṣé o lágbára bí èmi Ọlọrun,àbí o lè sán wàá bí ààrá, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀?