1 “Ṣé o lè fi ìwọ̀ fa Lefiatani jáde,tabi kí o fi okùn di ahọ́n rẹ̀?
2 Ṣé o lè fi okùn sí imú rẹ̀,tabi kí o fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní àgbọ̀n?
3 Ṣé yóo bẹ̀ ọ́,tabi kí ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀?
4 Ṣé yóo bá ọ dá majẹmu,pé kí o fi òun ṣe iranṣẹ títí lae?
5 Ṣé o lè máa fi ṣeré bí ọmọ ẹyẹ,tabi kí o dè é lókùn fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ?
6 Ṣé àwọn oníṣòwò lè yọwó rẹ̀?Àbí wọ́n lè pín Lefiatani láàrin ara wọn?
7 Ṣé o lè fi ọ̀kọ̀ gún ẹran ara rẹ̀,tabi kí o fi ẹ̀sín àwọn apẹja gún orí rẹ̀?