17 Wọ́n so pọ̀,wọ́n lẹ̀ mọ́ ara wọn tóbẹ́ẹ̀,tí ohunkohun kò lè ṣí wọn.
18 Bí ó bá sín, ìmọ́lẹ̀ á tàn jáde ní imú rẹ̀,ojú rẹ̀ ń tàn bíi ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ kutukutu.
19 Ahọ́n iná ń yọ lẹ́nu rẹ̀ bí iná tí ń ta jáde,bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n iná ń yọ lálá.
20 Èéfín ń jáde ní imú rẹ̀,bíi ti ìkòkò gbígbóná ati ìgbẹ́ tí ń jó.
21 Èémí tí ó ń mí jáde dàbí ògúnná,ahọ́n iná ń yọ ní ẹnu rẹ̀.
22 Kìkì agbára ni ọrùn rẹ̀,ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀.
23 Ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ pọ̀ mọ́ ara wọn,wọ́n lẹ̀ pọ̀, wọn kò sì ṣe é ṣí.