20 Èéfín ń jáde ní imú rẹ̀,bíi ti ìkòkò gbígbóná ati ìgbẹ́ tí ń jó.
21 Èémí tí ó ń mí jáde dàbí ògúnná,ahọ́n iná ń yọ ní ẹnu rẹ̀.
22 Kìkì agbára ni ọrùn rẹ̀,ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀.
23 Ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ pọ̀ mọ́ ara wọn,wọ́n lẹ̀ pọ̀, wọn kò sì ṣe é ṣí.
24 Ọkàn rẹ̀ le bí òkúta,ó le ju ọlọ lọ.
25 Bí ó bá dìde, ẹ̀rù á ba àwọn alágbára,wọn á bì sẹ́yìn, wọn á ṣubú lé ara wọn lórí.
26 Bí idà tilẹ̀ bá a, kò ràn án,bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀kọ̀, ati ọfà, ati ẹ̀sín.