21 Èémí tí ó ń mí jáde dàbí ògúnná,ahọ́n iná ń yọ ní ẹnu rẹ̀.
22 Kìkì agbára ni ọrùn rẹ̀,ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀.
23 Ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ pọ̀ mọ́ ara wọn,wọ́n lẹ̀ pọ̀, wọn kò sì ṣe é ṣí.
24 Ọkàn rẹ̀ le bí òkúta,ó le ju ọlọ lọ.
25 Bí ó bá dìde, ẹ̀rù á ba àwọn alágbára,wọn á bì sẹ́yìn, wọn á ṣubú lé ara wọn lórí.
26 Bí idà tilẹ̀ bá a, kò ràn án,bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀kọ̀, ati ọfà, ati ẹ̀sín.
27 Irin kò yàtọ̀ sí koríko lójú rẹ̀,idẹ sì dàbí igi tí ó ti rà.