26 Bí idà tilẹ̀ bá a, kò ràn án,bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀kọ̀, ati ọfà, ati ẹ̀sín.
27 Irin kò yàtọ̀ sí koríko lójú rẹ̀,idẹ sì dàbí igi tí ó ti rà.
28 Bí wọn ta á lọ́fà, kò ní torí rẹ̀ sá,àwọn òkúta kànnàkànnà dàbí àgékù koríko lójú rẹ̀.
29 Kùmọ̀ dàbí koríko lára rẹ̀,a sì máa fi ẹni tí ó ju ọ̀kọ̀ lù ú rẹ́rìn-ín.
30 Ìpẹ́ ikùn rẹ̀ dàbí àpáàdì tí ó mú,wọn ń fa ilẹ̀ tútù ya bí ọkọ́.
31 Ó mú kí ibú hó bí omi inú ìkòkò,ó ṣe òkun bí ìkòkò òróró ìpara.
32 Bí ó bá ń rìn lọ, ipa ọ̀nà rẹ̀ a máa hàn lẹ́yìn rẹ̀,eniyan á rò pé òkun ń hó bí ọṣẹ ni.