29 Kùmọ̀ dàbí koríko lára rẹ̀,a sì máa fi ẹni tí ó ju ọ̀kọ̀ lù ú rẹ́rìn-ín.
30 Ìpẹ́ ikùn rẹ̀ dàbí àpáàdì tí ó mú,wọn ń fa ilẹ̀ tútù ya bí ọkọ́.
31 Ó mú kí ibú hó bí omi inú ìkòkò,ó ṣe òkun bí ìkòkò òróró ìpara.
32 Bí ó bá ń rìn lọ, ipa ọ̀nà rẹ̀ a máa hàn lẹ́yìn rẹ̀,eniyan á rò pé òkun ń hó bí ọṣẹ ni.
33 Kò sí ohun tí a lè fi wé láyé,ẹ̀dá tí ẹ̀rù kì í bà.
34 Ó fojú tẹmbẹlu gbogbo ohun gíga,ó sì jọba lórí gbogbo àwọn ọmọ agbéraga.”