5 Ṣé o lè máa fi ṣeré bí ọmọ ẹyẹ,tabi kí o dè é lókùn fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ?
6 Ṣé àwọn oníṣòwò lè yọwó rẹ̀?Àbí wọ́n lè pín Lefiatani láàrin ara wọn?
7 Ṣé o lè fi ọ̀kọ̀ gún ẹran ara rẹ̀,tabi kí o fi ẹ̀sín àwọn apẹja gún orí rẹ̀?
8 Lọ fọwọ́ kàn án;kí o wo irú ìjà tí yóo bá ọ jà;o kò sì ní dán irú rẹ̀ wò mọ́ lae!
9 “Ìrètí ẹni tí ó bá fẹ́ bá a jà yóo di òfo,nítorí ojora yóo mú un nígbà tí ó bá rí i.
10 Ta ló láyà láti lọ jí i níbi tí ó bá sùn sí?Ta ló tó kò ó lójú?
11 Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un?Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé.