9 “Ìrètí ẹni tí ó bá fẹ́ bá a jà yóo di òfo,nítorí ojora yóo mú un nígbà tí ó bá rí i.
10 Ta ló láyà láti lọ jí i níbi tí ó bá sùn sí?Ta ló tó kò ó lójú?
11 Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un?Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé.
12 “N kò ní yé sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ̀ rẹ̀,tabi nípa agbára rẹ̀ tabi dídára ìdúró rẹ̀.
13 Ta ló tó bó awọ rẹ̀,tabi kí ó fi nǹkan gún igbá ẹ̀yìn rẹ̀?
14 Ta ló tó ya ẹnu rẹ̀?Gbogbo eyín rẹ̀ ni ó kún fún ẹ̀rù.
15 Ẹ̀yìn rẹ̀ kún fún ìpẹ́ tí ó dàbí apata,a tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ, wọ́n súnmọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí bí èdìdì.