20 Ní àkókò ìyàn,yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú.Ní àkókò ogun,yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.
21 Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́gàn,o kò ní bẹ̀rù nígbà tí ìparun bá dé.
22 Ninu ìparun ati ìyàn,o óo máa rẹ́rìn-ín,o kò ní bẹ̀rù àwọn ẹranko ìgbẹ́.
23 O kò ní kan àwọn òkúta ninu oko rẹ,àwọn ẹranko igbó yóo wà ní alaafia pẹlu rẹ.
24 O óo máa gbé ilé rẹ ní àìséwu.Nígbà tí o bá ka ẹran ọ̀sìn rẹ,kò ní dín kan.
25 Àwọn arọmọdọmọ rẹ yóo pọ̀,bí ewéko ninu pápá oko.
26 O óo di arúgbó kí o tó kú,gẹ́gẹ́ bí ọkà tií gbókí á tó kó o wá síbi ìpakà.