7 A bí eniyan sinu wahalabí ẹ̀ta iná tí ń ta sókè.
8 “Ní tèmi, n óo máa wá OLUWA,n óo fọ̀rọ̀ mi lé Ọlọrun lọ́wọ́;
9 ẹni tíí ṣe ohun ńlátí eniyan kò lè rídìí,ati àwọn ohun ìyanu tí kò lóǹkà.
10 A máa rọ òjò sórí ilẹ̀,a sì máa bomi rin oko.
11 A máa gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga,a sì máa pa àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ mọ́.
12 A máa da ète àwọn alárèékérekè rú,kí wọn má baà lè yọrí ètekéte wọn.
13 Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn;ó sì mú ète àwọn ẹlẹ́tàn wá sópin.