9 Àní, kí ó wó mi mọ́lẹ̀,kí ó mú mi, kí ó pa mí dànù.
10 Yóo jẹ́ ìtùnú fún mi;n óo sì láyọ̀ ninu ọpọlọpọ ìrora,nítorí pé n kò sẹ́ ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́.
11 Agbára wo ni mo ní,tí mo fi lè tún máa wà láàyè?Kí sì ni ìrètí mi, tí n óo fi tún máa ní sùúrù?
12 Agbára mi ha rí bí ti òkúta bí?Àbí ẹran ara mi jẹ́ idẹ?
13 Nítòótọ́, n kò ní agbára mọ́,bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní olùrànlọ́wọ́.
14 “Ẹni tí ó bá kọ̀tí kò ṣàánú ọ̀rẹ́ rẹ̀kò ní ìbẹ̀rù Olodumare.
15 Ṣugbọn, ẹ̀yin arakunrin mi,ẹlẹ́tàn ni yín, bíi odò àgbàrátí ó yára kún,tí ó sì tún yára gbẹ,