10 Kò ní pada sí ilé rẹ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kò ní mọ̀ ọ́n mọ́.
11 “Nítorí náà, n kò ní dákẹ́;n óo sọ ìrora ọkàn mi;n óo tú ìbànújẹ́ mi jáde.
12 Ṣé òkun ni mí ni, tabi erinmi,tí ẹ fi yan olùṣọ́ tì mí?
13 Nígbà tí mo wí pé,‘Ibùsùn mi yóo tù mí lára,ìjókòó mi yóo sì mú kí ara tù mí ninu ìráhùn mi’.
14 Nígbà náà ni ẹ̀yin tún wá fi àlá yín dẹ́rù bà mí,tí ẹ sì fi ìran pá mi láyà,
15 kí n lè fara mọ́ ọn péó sàn kí á lọ́ mi lọ́rùn pa,kí n sì lè yan ikúdípò pé kí n wà láàyè.
16 Ayé sú mi,n kò ní wà láàyè títí lae.Ẹ fi mí sílẹ̀,nítorí ọjọ́ ayé mi dàbí èémí lásán.