1 Bilidadi ará Ṣuha dáhùn pé,
2 “O óo ti sọ irú ọ̀rọ̀ wọnyi pẹ́ tó,tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ yóo sì dàbí afẹ́fẹ́ líle?
3 Ṣé Ọlọrun a máa yí ìdájọ́ po?Ṣé Olodumare a máa yí òdodo pada?
4 Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ dẹ́ṣẹ̀ ni,ó ti jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
5 Ṣugbọn bí o bá wá Ọlọrun,tí o sì sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Olodumare;
6 tí o bá jẹ́ ẹni mímọ́ ati olóòótọ́,dájúdájú OLUWA yóo dìde, yóo ràn ọ́ lọ́wọ́,yóo sì fi ibùgbé rere san ẹ̀san fún ọ.