1. Kro 1 YCE

Ìran Adamu títí Dé Orí Abrahamu

1 ADAMU, Seti, Enoṣi,

2 Kenani, Mahalaleeli, Jeredi,

3 Henoki, Metusela, Lameki,

4 Noa, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti,

5 Awọn ọmọ Jafeti; Gomeri, ati Magogu, ati Madai, ati Jafani, ati Tubali, ati Meṣeki, ati Tirasi,

6 Ati awọn ọmọ Gomeri; Aṣkenasi, ati Rifati, ati Togarma.

7 Ati awọn ọmọ Jafani; Eliṣa, ati Tarṣiṣi, Kittimu, ati Dodanimu.

8 Awọn ọmọ Hamu; Kuṣi, ati Misraimu, Puti, ati Kenaani.

9 Ati awọn ọmọ Kuṣi; Ṣeba, ati Hafila, ati Sabta, ati Raama, ati Sabteka. Ati awọn ọmọ Raama; Ṣeba ati Dedani.

10 Kuṣi si bi Nimrodu: on bẹ̀rẹ si di alagbara li aiye.

11 Misraimu si bi Ludimu, ati Anamimu, ati Lehabimu, ati Naftuhimu,

12 Ati Patrusimu, ati Kasluhimu, (lọdọ ẹniti awọn ara Filistia ti wá,) ati Kaftorimu.

13 Kenaani si bi Sidoni akọbi rẹ̀, ati Heti,

14 Ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Amori, ati awọn ara Girgaṣi,

15 Ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Arki, ati awọn ara Sini,

16 Ati awọn ara Arfadi, ati awọn ara Semari, ati awọn ara Hamati.

17 Awọn ọmọ Ṣemu; Elamu, ati Assuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu, ati Usi, ati Huli, ati Geteri, ati Meṣeki.

18 Arfaksadi si bi Ṣela; Ṣela si bi Eberi.

19 Ati fun Eberi li a bi ọmọkunrin meji: orukọ ọkan ni Pelegi; nitori li ọjọ rẹ̀ li a pin aiye niya: orukọ arakunrin rẹ̀ si ni Joktani.

20 Joktani si bi Almodadi, ati Ṣelefi, ati Hasarmafeti, ati Jera,

21 Ati Hadoramu, ati Usali, ati Dikla,

22 Ati Ebali, ati Abimaeli, ati Ṣeba,

23 Ati Ofiri, ati Hafila, ati Jobabu. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Joktani.

24 Ṣemu, Arfaksadi, Ṣela,

25 Eberi, Pelegi, Reu,

26 Serugu, Nahori, Tera,

27 Abramu; on na ni Abrahamu,

Ìran Iṣimaeli

28 Awọn ọmọ Abrahamu; Isaaki, ati Iṣmaeli.

29 Wọnyi ni iran wọn: akọbi Iṣmaeli, Nebaioti; ati Kedari, ati Adbeeli, ati Mibsamu,

30 Miṣma, ati Duma, Massa, Hadadi, ati Tema,

31 Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema. Wọnyi li awọn ọmọ Iṣmaeli.

32 Ati awọn ọmọ Ketura, obinrin Abrahamu: on bi Simrani, ati Jokṣani, ati Medani, ati Midiani, ati Iṣbaki, ati Ṣua. Ati awọn ọmọ Jokṣani: Ṣeba, ati Dedani.

33 Ati awọn ọmọ Midiani: Efa, ati Eferi, ati Henoki, ati Abida, ani Eldaa. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Ketura.

Àwọn Ìran Esau

34 Abrahamu si bi Isaaki. Awọn ọmọ Isaaki; Esau ati Israeli.

35 Awọn ọmọ Esau; Elifasi, Reueli, ati Jeusi, ati Jaalamu, ati Kora.

36 Awọn ọmọ Elifasi; Temani, ati Omari, Sefi, ati Gatamu, Kenasi, ati Timna, ati Amaleki.

37 Awọn ọmọ Reueli: Nahati, Sera, Ṣamma, ati Missa.

Àwọn tí ń gbé Edomu tẹ́lẹ̀

38 Ati awọn ọmọ Seiri; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana, ati Diṣoni, ati Esari, ati Diṣani.

39 Ati awọn ọmọ Lotani; Hori, ati Homamu: Timna si ni arabinrin Lotani.

40 Awọn ọmọ Ṣobali; Aliani, ati Manahati, ati Ebali, Ṣefi, ati Onamu. Ati awọn ọmọ Sibeoni; Aiah, ati Ana.

41 Awọn ọmọ Ana; Diṣoni. Ati awọn ọmọ Diṣoni; Amrani, ati Eṣbani, ati Itrani, ati Kerani.

42 Awọn ọmọ Eseri; Bilhani, ati Safani, ati Jakani. Awọn ọmọ Diṣani; Usi, ati Arani.

Àwọn Ọba Edomu

43 Wọnyi si ni awọn ọba ti o jẹ ni ilẹ Edomu, ki ọba kan to jẹ lori awọn ọmọ Israeli: Bela ọmọ Beori: orukọ ilu rẹ̀ si ni Dinhaba.

44 Nigbati Bela si kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra si jọba ni ipò rẹ̀.

45 Nigbati Jobabu kú, Huṣamu ti ilẹ awọn ara Temani si jọba ni ipò rẹ̀.

46 Nigbati Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi, ti o kọlu Midiani ni ìgbẹ Moabu, jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ ni Afiti.

47 Nigbati Hadadi kú, Samla ti Masreka jọba ni ipò rẹ̀.

48 Nigbati Samla kú, Ṣaulu ti Rehoboti leti odò jọba ni ipò rẹ̀.

49 Nigbati Ṣaulu kú, Baal-hanani, ọmọ Akbori, jọba ni ipò rẹ̀.

50 Nigbati Baal-hanani kú, Hadadi si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ ni Pai; orukọ aya rẹ̀ si ni Mehetabeeli, ọmọbinrin Matredi, ọmọbinrin Mesahabu.

51 Hadadi si kú. Awọn bãlẹ Edomu ni; Timna bãlẹ, Aliah bãlẹ, Jeteti bãlẹ.

52 Aholibama bãlẹ, Ela bãlẹ, Pinoni bãlẹ,

53 Kenasi bãlẹ, Temani bãlẹ, Mibsari bãlẹ,

54 Magdieli bãlẹ, Iramu bãlẹ. Wọnyi ni awọn bãlẹ Edomu.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29