1. Kro 23 YCE

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi

1 NIGBATI Dafidi gbó, ti o si kún fun ọjọ, o fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lori Israeli.

2 O si kó gbogbo awọn ijoye Israeli jọ, ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi.

3 A si ka awọn ọmọ Lefi lati ẹni ọgbọ̀n ọdun ati jù bẹ̃ lọ: iye wọn nipa ori wọn, ọkunrin kọkan sí jẹ ẹgbã mọkandilogun.

4 Ninu wọnyi, ẹgbã mejila ni lati ma bojuto iṣẹ ile Oluwa; ẹgbãta si nṣe olori ati onidajọ:

5 Ẹgbaji si jẹ adena: ẹgbaji si fi ohun-elo ti mo ṣe lati buyìn, yìn Oluwa.

6 Dafidi si pín wọn ni ẹgbẹgbẹ lãrin awọn ọmọ Lefi, eyini ni Gerṣoni, Kohati, ati Merari.

7 Ninu awọn ọmọ Gerṣoni ni Laadani, ati Ṣimei.

8 Awọn ọmọ Laadani: Jehieli ni olori, ati Setamu, ati Joeli, mẹta.

9 Awọn ọmọ Ṣimei; Ṣelomiti, ati Hasieli, ati Harani, mẹta. Awọn wọnyi li olori awọn baba Laadani.

10 Awọn ọmọ Ṣimei ni Jahati, Sina, ati Jeuṣi, ati Beriah. Awọn mẹrin wọnyi li ọmọ Ṣimei.

11 Jahati si li olori, ati Sisa ibikeji: ṣugbọn Jeuṣi ati Beriah kò li ọmọ pipọ; nitorina ni nwọn ṣe wà ni iṣiro kan, gẹgẹ bi ile baba wọn.

12 Awọn ọmọ Kohati; Amramu, Ishari, Hebroni ati Ussieli, mẹrin.

13 Awọn ọmọ Amramu; Aaroni ati Mose: a si ya Aaroni si ọ̀tọ, ki o le ma sọ awọn ohun mimọ́ jùlọ di mimọ́, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai, lati ma jo turari niwaju Oluwa, lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀ lailai.

14 Ṣugbọn niti Mose enia Ọlọrun, a kà awọn ọmọ rẹ̀ pọ̀ mọ ẹ̀ya Lefi.

15 Awọn ọmọ Mose ni, Gerṣomu ati Elieseri.

16 Ninu awọn ọmọ Gerṣomu, Sebueli li olori.

17 Awọn ọmọ Elieseri ni Rehabiah olori. Elieseri kò si li ọmọ miran; ṣugbọn awọn ọmọ Rehabiah pọ̀ gidigidi.

18 Ninu awọn ọmọ Ishari; Ṣelomiti li olori.

19 Ninu awọn ọmọ Hebroni: Jeriah ekini, Amariah ekeji, Jahasieli ẹkẹta, ati Jekamami ẹkẹrin.

20 Ninu awọn ọmọ Ussieli: Mika ekini, ati Jesiah ekeji.

21 Awọn ọmọ Merari; Mali ati Muṣi. Awọn ọmọ Mali; Eleasari ati Kiṣi.

22 Eleasari kú, kò si li ọmọkunrin bikòṣe ọmọbinrin: awọn arakunrin wọn awọn ọmọ Kiṣi si fẹ wọn li aiya.

23 Awọn ọmọ Muṣi; Mali, ati Ederi, ati Jeremoti, mẹta.

24 Wọnyi ni awọn ọmọ Lefi, bi ile baba wọn; ani olori awọn baba, bi a ti ka wọn ni iye orukọ, nipa ori wọn, awọn ti o ṣiṣẹ ìsin ile Oluwa, lati iwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ.

25 Nitori Dafidi wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli ti fi isimi fun awọn enia rẹ̀, on si ngbé Jerusalemu lailai:

26 Ati pẹlu awọn ọmọ Lefi: nwọn kì yio si tun rù ibugbe na mọ, ati gbogbo ohun elo rẹ̀ fun ìsin rẹ̀.

27 Nitori nipa ọ̀rọ ikẹhin Dafidi, ni kika iye awọn ọmọ Lefi lati ìwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ:

28 Nitori iṣẹ wọn ni lati duro tì awọn ọmọ Aaroni, fun ìsin ile Oluwa, niti àgbala, ati niti iyẹwu, ati niti ṣiṣe ohun èlo wọnni ni mimọ́, ati iṣẹ ìsin ile Ọlọrun;

29 Ati fun àkara ifihàn, ati fun iyẹfun kikuna fun ẹbọ ọrẹ, ati fun àkara alaiwu, ati fun eyi ti a yan ninu awo pẹtẹ, ati fun eyi ti a dín, ati fun gbogbo oniruru òṣuwọn ati ìwọn;

30 Ati lati duro li orowurọ lati dupẹ ati lati yin Oluwa, ati bẹ̃ gẹgẹ li aṣalẹ;

31 Ati lati ru gbogbo ẹbọ ọrẹ sisun fun Oluwa li ọjọjọ isimi, ati li oṣù titun ati li ọjọ wọnni ti a pa li aṣẹ, ni iye, li ẹsẹsẹ gẹgẹ bi aṣẹ ti a pa fun wọn nigbagbogbo niwaju Oluwa:

32 Ati ki nwọn ki o ma tọju ẹṣọ agọ ajọ enia, ati ẹṣọ ibi mimọ́, ati ẹṣọ awọn ọmọ Aaroni arakunrin wọn, ni ìsin ile Oluwa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29