1. Kro 11 YCE

Dafidi Jọba lórí Israẹli ati Juda

1 NIGBANA ni gbogbo Israeli ko ara wọn jọ si ọdọ Dafidi ni Hebroni, wipe, Kiyesi i, egungun rẹ ati ẹran ara rẹ li awa iṣe.

2 Ati pẹlu li atijọ, ani nigbati Saulu jẹ ọba, iwọ li o nmu Israeli jade ti o si nmu u wá ile: Oluwa Ọlọrun rẹ si wi fun ọ pe, Ki iwọ ki o bọ Israeli, enia mi, ki iwọ ki o si ṣe ọmọ-alade lori Israeli enia mi.

3 Nitorina ni gbogbo awọn agbagba Israeli ṣe tọ ọba wá ni Hebroni; Dafidi si ba wọn da majẹmu ni Hebroni niwaju Oluwa; nwọn si fi ororo yan Dafidi li ọba lori Israeli, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa nipa ọwọ Samueli.

4 Ati Dafidi ati gbogbo Israeli jade lọ si Jerusalemu, ti iṣe Jebusi; awọn Jebusi ara ilẹ na ngbe ibẹ̀.

5 Awọn ara ilu Jebusi si wi fun Dafidi pe, Iwọ kò gbọdọ wọ̀ ihinyi wa. Ṣugbọn Dafidi kó ilu odi Sioni ti iṣe ilu Dafidi.

6 Dafidi si wipe, Ẹnikẹni ti o ba tetekọ kọlù awọn ara Jebusi ni yio ṣe olori ati balogun. Bẹ̃ni Joabu ọmọ Seruiah si tetekọ gòke lọ, o si jẹ olori.

7 Dafidi si ngbe inu ilu odi, nitorina ni nwọn fi npè e ni ilu Dafidi.

8 O si kọ́ ilu na yikakiri; ani lati Millo yikakiri: Joabu si tun iyokù ilu na ṣe.

9 Bẹ̃ni Dafidi nga, o si npọ̀ si i: nitori ti Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu rẹ̀.

Àwọn Ọmọ Ogun Dafidi tí Wọ́n Jẹ́ Olókìkí

10 Wọnyi si ni olori awọn ọkunrin akọni ti Dafidi ni; awọn ti o fi ara wọn mọ ọ girigiri ni ijọba rẹ̀, pẹlu gbogbo Israeli, lati fi i jọba, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa fun Israeli.

11 Eyi ni iye awọn ọkunrin akọni ti Dafidi ni; Jaṣobeamu ọmọ Hakmoni, olori ninu awọn ọgbọ̀n balogun: on li o gbé ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun enia ti o pa lẹrikan.

12 Lẹhin rẹ̀ ni Eleaseri ọmọ Dodo, ara Ahohi, ẹniti iṣe ọkan ninu awọn akọni mẹta.

13 On wà pẹlu Dafidi ni Pasdammimu, nigbati awọn ara Filistia ko ara wọn jọ lati jagun, nibiti ilẹ-bĩri kan wà ti o kún fun ọkà barli; awọn enia si salọ kuro niwaju awọn ara Filistia.

14 Nwọn si duro jẹ li ãrin ilẹ-bĩri na, nwọn si gbà a, nwọn si pa awọn ara Filistia; Oluwa si fi igbala nla gbà wọn.

15 Awọn mẹta ninu awọn ọgbọ̀n balogun si sọ̀kalẹ tọ̀ Dafidi lọ sibi apata na, ninu iho Adullamu; ogun ara Filistia si do li afonifoji Refaimu.

16 Dafidi si mbẹ ninu ilu odi nigbana, ẹgbẹ-ogun awọn ara Filistia si mbẹ ni Betlehemu li akoko na.

17 Dafidi si pòngbẹ, o si wipe, Emi iba ri ẹni fun mi mu ninu omi kanga Betlehemu ti mbẹ leti ẹnu-bodè!

18 Awọn mẹta na si la inu ogun awọn ara Filistia kọja, nwọn si fa omi jade lati inu kanga Betlehemu, lati ẹnu-bodè, nwọn gbé e, nwọn si mu u tọ̀ Dafidi wá: Dafidi kò si fẹ mu u, ṣugbọn o tu u silẹ fun Oluwa,

19 O si wipe, Ki Ọlọrun mi má jẹ ki emi ki o ṣe eyi: ki emi ki o ha mu ẹ̀jẹ awọn ọkunrin wọnyi, ti nwọn fi ẹmi wọn wewu? nipa ẹmi wọn ni nwọn fi mu u wá. Nitorina ni on kò ṣe fẹ mu u, nkan wọnyi li awọn akọni mẹta wọnyi ṣe.

20 Ati Abiṣai arakunrin Joabu, on li olori ninu awọn mẹta: nitoriti o gbé ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun o pa wọn, o si ni orukọ ninu awọn mẹta.

21 O ni ọla jù awọn mẹta ẹgbẹ ekeji lọ o si jẹ olori wọn: ṣugbọn kò to awọn mẹta iṣaju.

22 Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkunrin kan ti Kabseeli, ẹniti o pọ̀ ni iṣe agbara, o pa awọn ọmọ Arieli meji ti Moabu; on sọkalẹ, o si pa kiniun kan ninu iho lakoko sno.

23 O si pa ara Egipti kan, ọkunrin ti o si sigbọnlẹ igbọnwọ marun ni gigun rẹ̀; ati li ọwọ ara Egipti na ni ọ̀kọ kan wà bi idubu igi awunṣọ; o si sọ̀kalẹ tọ ọ lọ pẹlu ọpa, a si já ọ̀kọ li ọwọ ara Egipti na, o si fi ọ̀kọ rẹ̀ pa a.

24 Nkan wọnyi ni Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, o si li orukọ ninu awọn akọni mẹta.

25 Kiyesi i, o li ọla jù awọn ọ̀gbọn lọ, ṣugbọn kò to awọn mẹta iṣaju. Dafidi si fi ṣe olori awọn igbimọ ile rẹ̀.

26 Awọn akọni ọkunrin ọmọ ogun rẹ̀ ni Asaheli arakunrin Joabu, Elhanani, ọmọ Dodo, ara Betlehemu.

27 Sammotu, ara Harori, Helesi, ara Peloni,

28 Ira, ọmọ Ikkeṣi, ara Tekoa, Abieseri ara Anatoti,

29 Sibbekai, ara Husa, Ilai, ara Ahohi,

30 Maharai, ara Netofa, Heledi ọmọ Baana, ara Netofa.

31 Itai ọmọ Ribai ti Gibea, ti awọn ọmọ Benjamini, Benaiah ara Piratoni,

32 Hurai ti odò Gaaṣi, Abieli ara Arbati,

33 Asmafeti ara Baharumi, Eliaba ara Ṣaalboni.

34 Awọn ọmọ Haṣemu ara Gisoni, Jonatani ọmọ Sage, ara Harari.

35 Ahihamu ọmọ Sakari, ara Harari, Elifali ọmọ Uri,

36 Heferi ara Mekerati, Ahijah ara Peloni,

37 Hesro ara Karmeli, Naari ọmọ Esbai,

38 Joeli arakunrin Natani, Mibhari ọmọ Haggeri,

39 Saleki ara Ammoni, Naharai ara Beroti, ẹniti nru ihamọra Joabu ọmọ Seruiah,

40 Ira ara Itri, Garobu ara Itri,

41 Uriah ara Heti, Sabadi ọmọ Ahalai,

42 Adina ọmọ Ṣisa ara Reubeni, olori awọn ara Reubeni, ati ọgbọ̀n enia pẹlu rẹ̀.

43 Hanani ọmọ Maaka, ati Jehoṣafati ara Mitini,

44 Ussia ara Aslerati, Ṣama ati Jegieli, awọn ọmọ Hotani, ara Aroeri,

45 Jediaeli ọmọ Simri, ati Joha arakunrin rẹ̀ ara Tisi,

46 Elieli ara Mahafi, ati Jeribai, ati Joṣafia, awọn ọmọ Elnaamu, ati Tima ara Moabu.

47 Elieli, ati Obedi, ati Jasieli ara Mesobah.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29