1. Kro 2 YCE

Àwọn Arọmọdọmọ Juda

1 WỌNYI ni awọn ọmọ Israeli; Rubeni, Simeoni, Lefi, ati Juda, Issakari, ati Sebuluni,

2 Dani, Josefu, ati Benjamini, Naftali, Gadi, ati Aṣeri.

3 Awọn ọmọ Juda; Eri, ati Onani, ati Ṣela; awọn mẹta yi ni Batṣua, ara Kenaani, bi fun u. Eri, akọbi Juda, si buru loju Oluwa; on si pa a.

4 Tamari aya-ọmọ rẹ̀ si bi Faresi ati Sera fun u. Gbogbo awọn ọmọ Juda jẹ marun.

5 Awọn ọmọ Faresi; Hesroni; ati Hamuli.

6 Ati awọn ọmọ Sera; Simri, ati Etani, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara: gbogbo wọn jẹ marun.

7 Ati awọn ọmọ Karmi; Akari, oniyọnu Israeli, ẹniti o dẹṣẹ niti ohun iyasọtọ̀.

8 Awọn ọmọ Etani; Asariah.

Ìran Dafidi Ọba

9 Awọn ọmọ Hesroni pẹlu ti a bi fun u; Jerahmeeli, ati Ramu, ati Kelubai.

10 Ramu si bi Amminadabu; Amminadabu si bi Naṣoni, ijoye awọn ọmọ Juda;

11 Naṣoni si bi Salma, Salma si bi Boasi.

12 Boasi si bi Obedi, Obedi si bi Jesse,

13 Jesse si bi Eliabu akọbi rẹ̀, ati Abinadabu àtẹle, ati Ṣimma ẹkẹta.

14 Netanneeli ẹkẹrin, Raddai ẹkarun,

15 Osemu ẹkẹfa, Dafidi ekeje:

16 Awọn arabinrin wọn ni Seruiah ati Abigaili. Ati awọn ọmọ Seruiah; Abiṣai, ati Joabu, ati Asaeli, mẹta.

17 Abigaili si bi Amasa: baba Amasa si ni Jeteri ara Iṣmeeli.

Ìran Hesironi

18 Kalebu ọmọ Hesroni si bi ọmọ lati ọdọ Asuba aya rẹ̀, ati lati ọdọ Jeriotu: awọn ọmọ rẹ̀ ni wọnyi; Jeṣeri, ati Ṣohabu, ati Ardoni.

19 Nigbati Asuba kú, Kalebu mu Efrati, ẹniti o bi Huri fun u.

20 Huri si bi Uru, Uru si bi Besaleeli.

21 Lẹhin na Hesroni si wọle tọ̀ ọmọ Makiri obinrin baba Gileadi, on gbe e ni iyawo nigbati o di ẹni ọgọta ọdun, on si bi Segubu fun u.

22 Segubu si bi Jairi, ti o ni ilu mẹtalelogun ni ilẹ Gileadi.

23 Ṣugbọn Geṣuri, ati Aramu, gbà ilu Jairi lọwọ wọn, pẹlu Kenati, ati ilu rẹ̀: ani ọgọta ilu. Gbogbo wọnyi ni awọn ọmọ Makiri baba Gileadi.

24 Ati lẹhin igbati Hesroni kú ni ilu Kaleb-Efrata, ni Abiah aya Hesroni bi Aṣuri baba Tekoa fun u.

Àwọn Ìran Jerameeli

25 Ati awọn ọmọ Jerahmeeli, akọbi Hesroni, ni Rama akọbi, ati Buna, ati Oreni, ati Osemu, ati Ahijah.

26 Jerahmeeli si ni obinrin miran pẹlu, orukọ ẹniti ijẹ Atara; on ni iṣe iya Onamu.

27 Awọn ọmọ Ramu akọbi Jerahmeeli ni, Maasi, ati Jamini, ati Ekeri.

28 Awọn ọmọ Onamu si ni, Ṣammai, ati Jada. Awọn ọmọ Ṣammai ni; Nadabu ati Abiṣuri.

29 Orukọ aya Abiṣuri si njẹ Abihaili, on si bi Abani, ati Molidi fun u.

30 Ati awọn ọmọ Nadabu; Seledi, ati Appaimu: ṣugbọn Seledi kú laini ọmọ.

31 Ati awọn ọmọ Appaimu; Iṣi. Ati awọn ọmọ Iṣi; Ṣeṣani. Ati awọn ọmọ Ṣeṣani. Ahlai.

32 Ati awọn ọmọ Jada arakunrin Ṣammai; Jeteri, ati Jonatani; Jeteri si kú laini ọmọ.

33 Awọn ọmọ Jonatani; Peleti, ati Sasa. Wọnyi ni awọn ọmọ Jerahmeeli.

34 Ṣeṣani kò si ni ọmọkunrin, bikọṣe ọmọbinrin. Ṣeṣani si ni iranṣẹ kan, ara Egipti, orukọ, ẹniti ijẹ Jarha.

35 Ṣeṣani si fi ọmọbinrin rẹ̀ fun Jarha iranṣẹ rẹ̀ li aya; on si bi Attai fun u.

36 Attai si bi Natani, Natani si bi Sabadi,

37 Sabadi si bi Eflali, Eflali si bi Obedi,

38 Obedi si bi Jehu, Jehu si bi Asariah,

39 Asariah si bi Helesi, Helesi si bi Elasa,

40 Elasa si bi Sisamai, Sisamai si bi Ṣallumu,

41 Ṣallumu si bi Jekamiah, Jekamiah si bi Eliṣama.

Àwọn Ìran Kalebu Yòókù

42 Awọn ọmọ Kalebu arakunrin Jerahmeeli si ni Meṣa akọbi rẹ̀, ti iṣe baba Sifi; ati awọn ọmọ Mareṣa baba Hebroni.

43 Awọn ọmọ Hebroni; Kora, ati Tappua, ati Rekemu, ati Ṣema.

44 Ṣema si bi Rahamu, baba Jorkeamu: Rekemu si bi Ṣammai.

45 Ati ọmọ Ṣammai ni Maoni: Maoni si ni baba Bet-suri.

46 Efa obinrin Kalebu si bi Harani, ati Mosa, ati Gasesi: Harani si bi Gasesi.

47 Ati awọn ọmọ Jahdai; Regemu, ati Jotamu, ati Geṣamu, ati Peleti, ati Efa, ati Ṣaafu.

48 Maaka obinrin Kalebu bi Ṣeberi, ati Tirhana.

49 On si bi Ṣaafa baba Madmana, Ṣefa baba Makbena, ati baba Gibea: ọmọbinrin Kalebu si ni Aksa.

50 Wọnyi li awọn ọmọ Kalebu ọmọ Huri, akọbi Efrata; Ṣobali baba Kirjat-jearimu,

51 Salma baba Bet-lehemu, Harefu baba Bet-gaderi.

52 Ati Ṣobali baba Kirjat-jearimu ni ọmọ; Haroe, ati idaji awọn ara Manaheti.

53 Ati awọn idile Kirjat-jearimu; awọn ara Itri, ati awọn ara Puti, ati awọn ara Ṣummati, ati awọn ara Misrai; lọdọ wọn li awọn ara Sareati, ati awọn ara Ẹstauli ti wá.

54 Awọn ọmọ Salma; Betlehemu, ati awọn ara Netofati, Ataroti, ile Joabu, ati idaji awọn ara Manahati, awọn ara Sori.

55 Ati idile awọn akọwe ti ngbe Jabesi; awọn ara Tira, awọn ara Ṣimeati, ati awọn ara Sukati. Wọnyi li awọn ara Keni ti o ti ọdọ Hemati wá, baba ile Rekabu.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29