1. Kro 4 YCE

Ìran Juda

1 AWỌN ọmọ Juda; Faresi, Hesroni, ati Karmi, ati Huri, ati Ṣobali.

2 Reaiah ọmọ Ṣobali si bi Jahati; Jahati si bi Ahumai, ati Lahadi. Wọnyi ni idile awọn ara Sora.

3 Awọn wọnyi li o ti ọdọ baba Etamu wá; Jesreeli ati Jisma, ati Jidbaṣi: orukọ arabinrin wọn si ni Selelponi:

4 Ati Penueli ni baba Gedori, ati Eseri baba Huṣa. Wọnyi ni awọn ọmọ Huri, akọbi Efrata, baba Betlehemu.

5 Aṣuri baba Tekoa si li aya meji, Hela ati Naara.

6 Naara si bi Ahusamu, ati Heferi, ati Temeni, ati Ahaṣtari fun u. Wọnyi li awọn ọmọ Naara.

7 Ati awọn ọmọ Hela ni Sereti, ati Jesoari, ati Etnani.

8 Kosi si bi Anubu, ati Sobeba, ati awọn idile Aharheli, ọmọ Harumu.

9 Jabesi si ṣe ọlọla jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ: iya rẹ̀ si pe orukọ rẹ̀ ni Jabesi, wipe, Nitoriti mo bi i pẹlu ibanujẹ.

10 Jabesi si ké pè Ọlọrun Israeli, wipe, Iwọ iba jẹ bukún mi nitõtọ, ki o si sọ àgbegbe mi di nla, ki ọwọ rẹ ki o si wà pẹlu mi, ati ki iwọ ki o má si jẹ ki emi ri ibi, ki emi má si ri ibinujẹ! Ọlọrun si mu ohun ti o tọrọ ṣẹ.

Àwọn ìdílé yòókù

11 Kelubu arakunrin Ṣua si bi Mehiri, ti iṣe baba Eṣtoni.

12 Eṣtoni si bi Bet-rafa, ati Pasea, ati Tehinna baba ilu Nahaṣi. Wọnyi li awọn ọkunrin Reka,

13 Ati awọn ọmọ Kenasi; Otnieli, ati Seraiah: ati awọn ọmọ Otnieli; Hatati.

14 Meonotai si bi Ofra: Seraiah si bi Joabu, baba Geharasimu; nitori oniṣọnà ni nwọn.

15 Ati awọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne; Iru, Ela, ati Naamu: ati awọn ọmọ Ela, ani Kenasi.

16 Ati awọn ọmọ Jehaleleeli; Sifu, ati Sifa, Tiria, ati Asareeli.

17 Ati awọn ọmọ Esra ni Jeteri, ati Meredi, ati Eferi, ati Jaloni: on si bi Miriamu, ati Ṣammai, ati Iṣba baba Eṣtemoa.

18 Aya rẹ̀ Jehudijah si bi Jeredi baba Gedori, ati Heberi baba Soke, ati Jekutieli baba Sanoa. Wọnyi si li awọn ọmọ Bitiah ọmọbinrin Farao ti Meredi mu li aya.

19 Ati awọn ọmọ aya Hodiah, arabinrin Nahamu, baba Keila, ara Garmi, ati Eṣtemoa ara Maaka:

20 Awọn ọmọ Ṣimoni si ni Amnoni, ati Rinna, Benhanani, ati Tiloni. Ati awọn ọmọ Iṣi ni, Soheti, ati Bensoheti,

Àwọn Ìran Ṣela

21 Awọn ọmọ Ṣela, ọmọ Juda ni, Eri baba Leka, ati Laada baba Mareṣa ati idile ile awọn ti nwọn nwun aṣọ ọ̀gbọ daradara, ti ile Aṣbea,

22 Ati Jokimu, ati awọn ọkunrin Koseba, ati Joaṣi, ati Sarafu, ti o ni ijọba ni Moabu, ati Jaṣubilehemu. Iwe iranti atijọ ni wọnyi.

23 Wọnyi li awọn amọkoko, ati awọn ti ngbe ãrin ọgba ti odi yika; nibẹ ni nwọn ngbe pẹlu ọba fun iṣẹ rẹ̀.

Àwọn Ìran Simeoni

24 Awọn ọmọ Simeoni ni, Nemueli, ati Jamini, Jaribi, Sera, Ṣauli:

25 Ṣallumu ọmọ rẹ̀, Mibsamu ọmọ rẹ̀, Miṣma ọmọ rẹ̀.

26 Ati awọn ọmọ Miṣma; Hammueli ọmọ rẹ̀, Sakkuri ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀.

27 Ṣimei si ni ọmọkunrin mẹrindilogun, ati ọmọbinrin mẹfa; ṣugbọn awọn arakunrin rẹ̀ kò ni ọmọkunrin pupọ, bẹ̃ni kì iṣe idile wọn gbogbo li o rẹ̀ gẹgẹ bi awọn ọmọ Juda.

28 Nwọn si ngbe Beerṣeba, ati Molada, ati Haṣari-ṣuali,

29 Ati ni Bilha, ati ni Esemu, ati ni Toladi,

30 Ati ni Betueli, ati ni Horma, ati ni Siklagi,

31 Ati ni Bet-markaboti, ati ni Hasar-susimu, ati ni Bet-birei, ati Ṣaaraimu. Awọn wọnyi ni ilu wọn, titi di ijọba Dafidi.

32 Ileto wọn si ni, Etamu, ati Aini, Rimmoni, ati Tokeni, ati Aṣani, ilu marun:

33 Ati gbogbo ileto wọn, ti o wà yi ilu na ka, de Baali. Wọnyi ni ibugbe wọn, ati itan idile wọn.

34 Ati Meṣobabu ati Jamleki, ati Joṣa ọmọ Amasiah.

35 Ati Joeli, ati Jehu ọmọ Josibiah, ọmọ Seraiah, ọmọ Asieli,

36 Ati Elioenai, ati Jaakoba, ati Jeṣohaiah, ati Asaiah, ati Adieli, ati Jesimieli, ati Benaiah,

37 Ati Sisa ọmọ Ṣifi, ọmọ Alloni, ọmọ Jedaiah, ọmọ Ṣimri ọmọ Ṣemaiah;

38 Awọn ti a darukọ wọnyi, ìjoye ni wọn ni idile wọn: ile baba wọn si tan kalẹ gidigidi.

39 Nwọn si wọ̀ oju-ọ̀na Gedori lọ, titi de apa ariwa afonifoji na, lati wá koriko fun agbo ẹran wọn.

40 Nwọn si ri koriko tutù ti o si dara; ilẹ na si gbàye, o si gbe jẹ, o si wà li alafia: nitori awọn ọmọ Hamu li o ti ngbe ibẹ li atijọ.

41 Ati awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn, dé li ọjọ Hesekiah ọba Juda, nwọn si kọlu agọ wọn, ati pẹlu awọn ara Mehuni ti a ri nibẹ, nwọn si bà wọn jẹ patapata titi di oni yi, nwọn si ngbe ipò wọn: nitori koriko mbẹ nibẹ fun agbo ẹran wọn.

42 Omiran ninu wọn, ani ninu awọn ọmọ Simeoni, ẹ̃dẹgbẹta ọkunrin, lọ si òke Seiri, nwọn ni Pelatiah, ati Neariah, ati Refaiah ati Ussieli, awọn ọmọ Iṣi li olori wọn.

43 Nwọn si kọlù iyokù awọn ara Amaleki, ti nwọn salà, nwọn si ngbe ibẹ titi di oni yi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29