1 NITI ipin awọn adena: niti awọn ọmọ Kosa ni Meṣelemiah ọmọ Kore, ninu awọn ọmọ Asafu.
2 Ati awọn ọmọ Meṣelemiah ni Sekariah akọbi, Jediaeli ekeji, Sebadiah ẹkẹta, Jatnieli ẹkẹrin,
3 Elamu ẹkarun, Johanani ẹkẹfa, Elioenai ekeje.
4 Awọn ọmọ Obed-Edomu si ni Ṣemaiah akọbi, Jehosabadi ekeji, Joa ẹkẹta, ati Sakari ẹkẹrin, ati Netaneeli ẹkarun,
5 Ammieli ẹkẹfa, Issakari ekeje, Peulltai ẹkẹjọ: Ọlọrun sa bukún u.
6 Ati fun Ṣemaiah ọmọ rẹ̀ li a bi awọn ọmọ ti nṣe olori ni ile baba wọn: nitori alagbara akọni enia ni nwọn.
7 Awọn ọmọ Ṣemaiah; Otni, ati Refaeli, ati Obedi, Elsabadi, arakunrin ẹniti iṣe alagbara enia, Elihu, ati Semakiah.
8 Gbogbo wọnyi ti inu awọn ọmọ Obed-Edomu, ni: awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn arakunrin wọn, akọni enia ati alagbara fun ìsin na, jẹ mejilelọgọta lati ọdọ Obed-Edomu;
9 Meṣelemiah si ni awọn ọmọ ati arakunrin, alagbara enia, mejidilogun.
10 Hosa pẹlu, ninu awọn ọmọ Merari, ni ọmọ; Simri olori (nitori bi on kì iti iṣe akọbi ṣugbọn baba rẹ̀ fi jẹ olori),
11 Hilkiah ekeji, Tebaliah ẹkẹta, Sekariah ẹkẹrin: gbogbo awọn ọmọ ati awọn arakunrin Hosa jẹ mẹtala.
12 Ninu awọn wọnyi ni ipin awọn adena, ani ninu awọn olori ọkunrin, ti nwọn ni iṣẹ gẹgẹ bi awọn arakunrin wọn, lati ṣe iranṣẹ ni ile Oluwa.
13 Nwọn si ṣẹ keké, bi ti ẹni-kekere bẹ̃ni ti ẹni-nla, gẹgẹ bi ile baba wọn, fun olukuluku ẹnu-ọ̀na.
14 Iṣẹ keké iha ila-õrun bọ̀ sọdọ Ṣelemiah. Nigbana ni nwọn ṣẹ keké fun Sekariah ọmọ rẹ̀, ọlọgbọ́n igbimọ; iṣẹ keké rẹ̀ si bọ si iha ariwa.
15 Sọdọ Obed-Edomu niha gusù; ati sọdọ awọn ọmọ rẹ̀ niha ile Asuppimu (yara iṣura).
16 Ti Suppimu ati Hosa niha iwọ-õrun li ẹnu-ọ̀na Ṣalleketi, nibi ọ̀na igòke lọ, iṣọ kọju si iṣọ.
17 Niha ìla-õrùn awọn ọmọ Lefi mẹfa (nṣọ), niha ariwa mẹrin li ojojumọ, niha gusù mẹrin li ojojumọ, ati ninu Asuppimu (ile iṣura) mejimeji.
18 Ni ibasa niha iwọ-õrùn, mẹrin li ọ̀na igòke-lọ ati meji ni ibasa.
19 Wọnyi ni ipin awọn adena lati inu awọn ọmọ Kore, ati lati inu awọn ọmọ Merari.
20 Lati inu awọn ọmọ Lefi, Ahijah li o wà lori iṣura ile Ọlọrun, ati lori iṣura nkan wọnni ti a yà si mimọ́.
21 Awọn ọmọ Laadani; awọn ọmọ Laadani ara Gerṣoni, awọn olori baba, ani ti Laadani ara Gerṣoni ni Jehieli.
22 Awọn ọmọ Jehieli; Setamu, ati Joeli arakunrin rẹ̀, ti o wà lori iṣura ile Oluwa.
23 Ninu ọmọ Amramu, ati ọmọ Ishari, ara Hebroni, ati ọmọ Ussieli:
24 Ati Ṣebueli ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, ni onitọju iṣura.
25 Ati awọn arakunrin rẹ̀ nipa Elieseri, Rehabiah ọmọ rẹ̀, ati Jesaiah ọmọ rẹ̀, ati Joramu, ọmọ rẹ̀, ati Sikri ọmọ rẹ̀, ati Ṣelomiti ọmọ rẹ̀.
26 Ṣelomiti yi ati awọn arakunrin rẹ̀ li o wà lori iṣura ohun iyà-si-mimọ́, ti Dafidi ọba ati awọn olori baba, awọn ijoye lori ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati awọn olori ogun ti yà-si-mimọ́.
27 Lati inu ikogun ti a kó li ogun, ni nwọn yà si mimọ́ lati ma fi ṣe itọju ile Oluwa.
28 Ati gbogbo eyiti Samueli, ariran, ati Saulu, ọmọ Kiṣi, ati Abneri ọmọ Neri, ati Joabu ọmọ Seruiah, yà si mimọ́; gbogbo ohun ti a ba ti yà si mimọ́, ohun na mbẹ li ọwọ Ṣelomiti, ati awọn arakunrin rẹ̀.
29 Ninu awọn ọmọ Ishari, Kenaniah ati awọn ọmọ rẹ̀ li o jẹ ijoye ati onidajọ fun iṣẹ ilu lori Israeli.
30 Ninu awọn ọmọ Hebroni, Hasabiah ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn akọni enia, ẽdẹgbẹsan li awọn alabojuto Israeli nihahin Jordani niha iwọ-õrun, fun gbogbo iṣẹ Oluwa, ati fun ìsin ọba.
31 Ninu awọn ọmọ Hebroni ni Jerijah olori, ani ninu awọn ọmọ Hebroni, gẹgẹ bi idile ati iran awọn baba rẹ̀. Li ogoji ọdun ijọba Dafidi, a wá wọn, a si ri ninu wọn, awọn alagbara akọni enia ni Jaseri ti Gileadi.
32 Ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn akọni enia, jẹ ẹgbã o le ẽdẹgbẹrin: gbogbo wọn jẹ awọn olori baba ti Dafidi ọba fi ṣe olori lori awọn ọmọ Rubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, fun gbogbo ọ̀ran ti Ọlọrun ati ti ọba.