1. Kro 8 YCE

Àwọn Ìran Bẹnjamini

1 BENJAMINI si bi Bela, akọbi rẹ̀, Aṣbeli ekeji, ati Ahara ẹkẹta,

2 Noha ẹkẹrin, ati Rafa ẹkarun.

3 Awọn ọmọ Bela ni Addari, ati Gera, ati Abihudi,

4 Ati Abiṣua, ati Naamani, ati Ahoa,

5 Ati Gera, ati Ṣefufani, ati Huramu,

6 Wọnyi si li awọn ọmọ Ehudi: wọnyi li awọn olori baba wọn, ti nwọn ngbe Geba, nwọn si ko wọn lọ si Mahanati ni igbekun.

7 Ati Naamani, ati Ahiah, ati Gera, o si ko wọn kuro, o si bi Ussa ati Ahihudi.

8 Ṣaharaimu si bi ọmọ ni ilẹ Moabu; lẹhin igbati o ti ran wọn lọ tan; Huṣimu ati Baera si li awọn aya rẹ̀.

9 Hodeṣi, aya rẹ̀ si bi, Jobabu, ati Sibia, ati Meṣa, ati Malkama fun u,

10 Ati Jeusi, ati Ṣokia, ati Mirma. Wọnyi li awọn ọmọ rẹ̀, olori awọn baba.

11 Huṣimu si bi Ahitubu ati Elpaali fun u.

12 Awọn ọmọ Elpaali, Eberi, ati Miṣamu ati Ṣameri, ẹniti o kọ́ Ono ati Lodi pẹlu ilu wọn:

Àwọn Ará Bẹnjamini tí wọ́n wà ní Gati ati Aijalonii

13 Beria pẹlu, ati Ṣema, ti nwọn iṣe olori awọn baba awọn ara Ajaloni, awọn ti o le awọn ara Gati kuro.

14 Ati Ahio, Ṣaṣaki, Jerimotu,

15 Ati Sebadiah, ati Aradi, ati Aderi,

16 Ati Mikaeli, ati Ispa, ati Joha, ni awọn ọmọ Beria;

Àwọn Ará Bẹnjamini ní Jerusalẹmu

17 Ati Sobadiah, ati Meṣullamu, ati Heseki, ati Heberi.

18 Iṣmeri pẹlu, ati Jeslia, ati Jobabu, ni awọn ọmọ Elpaali.

19 Ati Jakimu, ati Sikri, ati Sabdi,

20 Ati Elienai, ati Siltai, ati Elieli,

21 Ati Adaiah, ati Beraiah, ati Ṣimrati ni awọn ọmọ Ṣimhi;

22 Ati Iṣpani, ati Eberi, ati Elieli,

23 Ati Abdoni, ati Sikri, ati Hanani,

24 Ati Hananiah, ati Elamu, ati Antotiah,

25 Ati Ifediah, ati Penueli, ni awọn ọmọ Ṣaṣaki;

26 Ati Samṣerai, ati Sehariah, ati Ataliah,

27 Ati Jaresiah, ati Eliah, ati Sikri, ni awọn ọmọ Jerohamu.

28 Wọnyi li olori awọn baba, nipa iran wọn, awọn olori. Awọn wọnyi ni ngbe Jerusalemu.

Àwọn Ará Bẹnjamini tí Wọ́n Wà ní Gibeoni ati Jerusalẹmu

29 Ni Gibeoni ni baba Gibeoni si ngbe; orukọ aya ẹniti ijẹ Maaka:

30 Ọmọ rẹ̀ akọbi si ni Abdoni, ati Suri, ati Kiṣi, ati Baali, ati Nadabu,

31 Ati Gedori, ati Ahio, ati Sakeri,

32 Mikloti si bi Ṣimea. Awọn wọnyi pẹlu si mba awọn arakunrin wọn gbe Jerusalemu, nwọn kọju si ara wọn.

Ìdílé Saulu Ọba

33 Neri si bi Kiṣi, ati Kiṣi si bi Saulu, ati Saulu si bi Jonatani, ati Milkiṣua, ati Abinadabu, ati Esbaali.

34 Ọmọ Jonatani si ni Meribaali; Meribaali si bi Mika.

35 Awọn ọmọ Mika ni Pitoni ati Meleki, ati Tarea, ati Ahasi.

36 Ahasi si bi Jehoadda; ati Jehoadda si bi Alemeti, ati Asmafeti, ati Simri: Simri si bi Mosa;

37 Mosa si bi Binea, Rafa ọmọ rẹ̀, Eleasari ọmọ rẹ̀, Aseli ọmọ rẹ̀:

38 Aseli si ni ọmọkunrin mẹfa, orukọ wọn ni wọnyi, Asrikamu, Bokeru, ati Iṣmaeli, ati Seraiah, ati Obadiah, ati Hanani. Gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Aseli.

39 Awọn ọmọ Eṣeki arakunrin rẹ̀ si ni Ulamu akọbi rẹ̀, Jehuṣi ekeji, ati Elifeleti ẹkẹta.

40 Awọn ọmọ Ulamu si jẹ alagbara akọni ọkunrin, tafatafa, nwọn si li ọmọ pupọ ati ọmọ ọmọ adọjọ. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Benjamini.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29