1. Kro 12 YCE

Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ Jẹ́ Ọmọlẹ́yìn Dafidi Ọba láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini

1 WỌNYI si li awọn ti o tọ̀ Dafidi wá si Siklagi, nigbati o fi ara rẹ̀ pamọ, nitori Saulu ọmọ Kiṣi: awọn wọnyi si wà ninu awọn akọni ti nṣe oluranlọwọ ogun na.

2 Nwọn le tafa, nwọn si le fi ọwọ ọtún ati ọwọ ọ̀si sọ okuta, ati fi ọrun tafa, ani ninu awọn arakunrin Saulu ti Benjamini.

3 Ahieseri ni olori, ati Joaṣi, awọn ọmọ Ṣemaa ara Gibea; ati Jesieli ati Peleti, awọn ọmọ Asmafeti; ati Beraka, ati Jehu ara Anatoti,

4 Ati Ismaiah ara Gibeoni, akọni ninu awọn ọgbọ̀n, ati lori ọgbọ̀n (enia) ati Jeremiah, ati Jahasieli, ati Johanani, ati Josabadi ara Gedera.

5 Elusai ati Jeremoti, ati Bealiah, ati Ṣemariah, ati Ṣefatiah ara Harofi,

6 Elkana, ati Jesiah, ati Asareelti ati Joeseri, ati Jaṣobeamu, awọn ara Kora,

7 Ati Joela, ati Sebadiah, awọn ọmọ Jerohamu ti Gedori.

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dafidi láti Inú Ẹ̀yà Gadi

8 Ati ninu awọn ara Gadi, awọn ọkunrin akọni kan ya ara wọn sọdọ Dafidi ninu iho ni iju, awọn ọkunrin ogun ti o yẹ fun ija ti o le di asà on ọ̀kọ mu, oju awọn ẹniti o dabi oju kiniun, nwọn si yara bi agbọnrin lori awọn òke nla;

9 Eseri ekini, Obadiah ekeji, Eliobu ẹkẹta,

10 Miṣmanna ẹkẹrin, Jeremiah ẹkarun,

11 Attai ẹkẹfa, Elieli ekeje,

12 Johanani ẹkẹjọ, Elsabadi ẹkẹsan,

13 Jeremiah ẹkẹwa, Makbanai ẹkọkanla.

14 Awọn wọnyi li awọn ọmọ Gadi, awọn olori ogun: ẹniti o kere jù to fun ọgọrun enia, ati ẹniti o pọ̀ju to fun ẹgbẹrun.

15 Wọnyi li awọn ti o gòke odò Jordani li oṣù ekini, nigbati o kún bò gbogbo bèbe rẹ̀; nwọn si le gbogbo awọn ti o wà li afonifoji ninu ila-õrùn, ati niha iwọ-õrùn.

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dafidi láti Inú Ẹ̀yà Bẹnjamini ati Ẹ̀yà Juda

16 Ninu awọn ọmọ Benjamini ati Juda si tọ Dafidi wá lori òke.

17 Dafidi si jade lọ ipade wọn, o si dahun o si wi fun wọn pe, Bi o ba ṣepe ẹnyin tọ̀ mi wá li alafia lati ràn mi lọwọ, ọkàn mi yio ṣọkan pẹlu nyin: ṣugbọn bi o ba ṣepe ẹnyin wá lati fi mi hàn fun awọn ọta mi, nigbati ẹbi kò si lọwọ mi, ki Ọlọrun awọn baba wa ki o wò o, ki o si ṣe idajọ.

18 Nigbana ni ẹmi bà lé Amasai, ti iṣe olori awọn ọgbọn na, wipe, Tirẹ li awa, Dafidi, tirẹ li a si nṣe, iwọ ọmọ Jesse: alafia! alafia ni fun ọ! alafia si ni fun awọn oluranlọwọ rẹ; nitori Ọlọrun rẹ ni nràn ọ lọwọ. Dafidi si gbà wọn, o si fi wọn jẹ olori ẹgbẹ-ogun.

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dafidi láti Inú Ẹ̀yà Manase

19 Ninu ẹyà Manasse si ya si ọdọ Dafidi, nigbati o ba awọn ara Filistia wá lati ba Saulu jagun, ṣugbọn nwọn kò ràn wọn lọwọ: nitori awọn olori awọn ara Filistia, nigbati nwọn gbero, rán a lọ wipe, Ti on ti ori wa ni on o fi pada lọ si ọdọ Saulu oluwa rẹ̀.

20 Bi on ti lọ si Siklagi, ninu awọn ẹya Manasse ya si ọdọ rẹ̀, Adna, ati Josabadi, Jediaeli, ati Mikaeli, ati Josabadi ati Elihu, ati Sittai, awọn olori ẹgbẹgbẹrun ti iṣe ti Manasse.

21 Nwọn si ràn Dafidi lọwọ si ẹgbẹ ogun na; nitori gbogbo wọn ni akọni enia, nwọn si jẹ olori ninu awọn ọmọ-ogun.

22 Nitori li akokò na li ojojumọ ni nwọn ntọ Dafidi wá lati ran a lọwọ, titi o fi di ogun nla, gẹgẹ bi ogun Ọlọrun.

Àwọn Ọmọ Ogun Dafidi

23 Eyi ni iye awọn enia na ti o hamọra tan fun ogun, ti nwọn si tọ̀ Dafidi wá si Hebroni, lati pa ijọba Saulu da si ọdọ rẹ̀ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.

24 Awọn ọmọ Juda ti ngbe asa ati ọ̀kọ, jẹ ẹgbãta enia o le ẹgbẹrin, ti o hamọra tan fun ogun.

25 Ninu awọn ọmọ Simeoni, akọni enia fun ogun ẹ̃dẹgbarin o le ọgọrun.

26 Ninu awọn ọmọ Lefi, ẹgbãji o le ẹgbẹta.

27 Jehoiada olori fun Aaroni, ẹgbẹ̃dogun enia o le ẽdẹgbẹrin si wà pẹlu rẹ̀.

28 Ati Sadoku, akọni ọdọmọkunrin, ati ninu ile baba rẹ̀ olori mejilelogun.

29 Ati ninu awọn ọmọ Benjamini, awọn arakunrin Saulu ẹgbẹ̃dogun: nitori titi di isisiyi, ọ̀pọlọpọ ninu wọn li o ti ntọju iṣọ ile Saulu.

30 Ati ninu awọn ọmọ Efraimu ẹgbãwa o le ẹgbẹrin, akọni ọkunrin, enia olorukọ ni nwọn ni ile baba wọn.

31 Ati àbọ ẹ̀ya Manasse ẹgbãsan, ti a yan nipa orukọ, lati lọ fi Dafidi jẹ ọba.

32 Ati ninu awọn ọmọ Issakari, ti o ni oye akoko, lati mọ̀ ohun ti Israeli iba ma ṣe; olori wọn jẹ igba; ati gbogbo awọn arakunrin wọn mbẹ ni ikawọ wọn.

33 Ninu ti Sebuluni, iru awọn ti o jade lọ si ogun ti o mọ̀ ogun iwé, pẹlu gbogbo ohun èlo ogun, ẹgbamẹ̃dọgbọn; ti nwọn kì ifi iye-meji tẹgun.

34 Ati ninu ti Naftali ẹgbẹrun olori ogun, ati pẹlu wọn ti awọn ti asa ati ọ̀kọ ẹgbã mejidilogun o le ẹgbẹrun.

35 Ati ninu awọn ọmọ Dani ti o mọ̀ ogun iwé, ẹgbã mẹtala o le ẹgbẹta.

36 Ati ninu ti Aṣeri, iru awọn ti njade lọ si ogun, ti o mọ̀ ogun iwé, ọkẹ meje.

37 Ati li apa keji odò Jordani, ninu ti awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati abọ ẹya Manasse, pẹlu gbogbo onirũru ohun elo ogun fun ogun ọ̀kọ, ọkẹ mẹfa.

38 Gbogbo awọn ọkunrin ogun wọnyi ti nwọn mọ̀ bi a iti itẹ ogun, nwọn fi ọkàn pipe wá si Hebroni, lati fi Dafidi jọba lori Israeli: gbogbo awọn iyokù ninu Israeli si jẹ oninu kan pẹlu lati fi Dafidi jẹ ọba.

39 Nibẹ, ni nwọn si wà pẹlu Dafidi ni ijọ mẹta, nwọn njẹ, nwọn si nmu, nitoriti awọn ará wọn ti pèse fun wọn.

40 Pẹlupẹlu awọn ti o sunmọ wọn, ani titi de ọdọ Issakari, ati Sebuluni, ati Naftali, mu akara wá lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ibakasiẹ, ati lori ibãka, ati lori malu, ani onjẹ ti iyẹfun, eso ọ̀pọtọ, ati eso àjara gbigbẹ, ati ọti-waini, ati ororo, ati malu, ati agutan li ọ̀pọlọpọ: nitori ti ayọ̀ wà ni Israeli.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29