1 DAFIDI si kó gbogbo ijoye Israeli jọ, awọn ijoye ẹ̀ya, ati awọn ijoye awọn ẹgbẹ ti nṣe iranṣẹ fun ọba, ati awọn ijoye lori ẹgbẹgbẹrun, ati awọn ijoye lori ọrọrun, ati awọn ijoye lori gbogbo ọrọ̀ ati ini ọba, ati ti awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu awọn balogun, ati pẹlu awọn alagbara enia, ati gbogbo akọni enia si Jerusalemu.
2 Nigbana ni Dafidi ọba dide duro li ẹsẹ rẹ̀, o si wipe, Ẹ gbọ́ ti emi, ẹnyin arakunrin mi ati enia mi: emi fẹ li ọkàn mi lati kọ́ ile isimi kan fun apoti ẹri majẹmu Oluwa, ati fun itisẹ Ọlọrun wa, mo si ti mura tan fun kikọ́le na:
3 Ṣugbọn Ọlọrun sọ fun mi pe, Iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitori ologun ni iwọ, o si ti ta ẹ̀jẹ silẹ.
4 Oluwa Ọlọrun Israeli si yàn mi lati inu gbogbo ile baba mi lati jẹ ọba lori Israeli lailai: nitori ti o ti yàn Juda li olori; ati ninu ile Juda, ile baba mi: ati larin awọn ọmọ baba mi o fẹ mi lati jẹ ọba gbogbo Israeli.
5 Ati ninu gbogbo ọmọ mi ọkunrin (nitori ti Oluwa ti fun mi li ọmọkunrin pupọ), o ti yàn Solomoni ọmọ mi lati joko lori itẹ ijọba Oluwa lori Israeli.
6 On si wi fun mi pe, Solomoni ọmọ rẹ, on yio kọ́ ile mi ati agbala mi: nitori emi ti yàn a li ọmọ mi, emi o si jẹ baba fun u.
7 Pẹlupẹlu emi o fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ lailai, bi o ba murale lati ṣe ofin mi ati idajọ mi bi li oni yi.
8 Njẹ nisisiyi li oju gbogbo Israeli ijọ enia Oluwa, ati li eti Ọlọrun wa, ẹ ma pamọ́ ki ẹ si ma ṣafẹri gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun nyin: ki ẹ le ni ilẹ rere yi, ki ẹ si le fi i silẹ li ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin lailai.
9 Ati iwọ, Solomoni ọmọ mi, mọ̀ Ọlọrun baba rẹ, ki o si fi aiya pipé ati fifẹ ọkàn sìn i: nitori Oluwa a ma wá gbogbo aiya, o si mọ̀ gbogbo ete ironu: bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀, iwọ o ri i; ṣugbọn bi iwọ ba kọ̀ ọ silẹ on o ta ọ nù titi lai.
10 Wò o nisisiyi: nitori Oluwa ti yàn ọ lati kọ́ ile kan fun ibi mimọ́, mura le, ki iwọ si ṣe e.
11 Nigbana ni Dafidi fi apẹrẹ fun Solomoni ọmọ rẹ̀ ti iloro, ati ti ile rẹ̀, ati ti ibi iṣura rẹ̀, ati ti iyara-òke rẹ̀, ati ti gbangan inu rẹ̀ ati ti ibi ibujoko ãnu,
12 Ati apẹrẹ gbogbo eyi ti o ni ni inu rẹ̀ pẹlu rẹ̀ niti agbala ile Oluwa, ati ti gbogbo iyara yikakiri, niti ibi iṣura ile Ọlọrun, ati niti ibi iṣura ohun ti a yà-si-mimọ́:
13 Niti ipin awọn alufa pẹlu ati ti awọn ọmọ Lefi, ati niti gbogbo iṣẹ ìsin ile Oluwa, ati niti gbogbo ohun èlo ìsin ni ile Oluwa.
14 Niti wura nipa ìwọn ti wura, niti gbogbo ohun èlo oniruru ìsin; niti gbogbo ohun èlo fadakà nipa ìwọn, niti gbogbo ohun èlo fun oniruru ìsin:
15 Ati ìwọn ọpa fitila wura, ati fitila wura wọn, nipa ìwọn fun olukuluku ọpa fitila ati ti fitila rẹ̀: ati niti ọpa fitila fadakà nipa ìwọn, ti olukuluku ọpa fitila ati ti fitila rẹ̀, gẹgẹ bi ìlo olukuluku ọpa fitila.
16 Ati wura nipa ìwọn fun tabili àkara ifihan, fun olukuluku tabili; ati fadakà fun tabili fadakà:
17 Ati wura didara fun pàlaka mimu ẹran, ati ọpọn, ati ago: ati fun awo-koto wura nipa ìwọn fun olukuluku awo-koto; ati nipa ìwọn fun olukuluku awo-koto fadakà:
18 Ati fun pẹpẹ turari, wura daradara nipa ìwọn; ati apẹrẹ iduro awọn kerubu ti wura, ti nwọn nà iyẹ wọn, ti nwọn si bo apoti ẹri majẹmu Oluwa mọlẹ
19 Gbogbo eyi wà ninu iwe lati ọwọ Oluwa ẹniti o kọ́ mi niti gbogbo iṣẹ apẹrẹ wọnyi.
20 Dafidi si sọ fun Solomoni ọmọ rẹ̀ pe, murale ki o si gboyà, ki o si ṣiṣẹ: má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki o máṣe dãmu: nitori Oluwa Ọlọrun, ani Ọlọrun mi wà pẹlu rẹ; on kì yio yẹ̀ ọ, bẹ̃ni kì yio kọ̀ ọ silẹ titi iwọ o fi pari gbogbo iṣẹ fun ìsin ile Oluwa.
21 Si kiyesi i, ipin awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, wà pẹlu rẹ fun oniruru ìsin ile Ọlọrun: iwọ ni pẹlu rẹ oniruru enia, ọlọkàn fifẹ, ẹniti o ni oye gbogbo iṣẹ fun oniruru iṣẹ: pẹlupẹlu awọn ijoye ati gbogbo awọn enia wà pẹlu rẹ fun gbogbo ọ̀ran rẹ.