1. Kro 21 YCE

Dafidi Ṣe Ètò Ìkànìyàn

1 SATANI si duro tì Israeli, o si tì Dafidi lati ka iye Israeli.

2 Dafidi si wi fun Joabu ati awọn olori enia pe, Lọ ikaye Israeli lati Beerṣeba titi de Dani; ki o si mu iye wọn fun mi wá, ki emi ki o le mọ̀ iye wọn.

3 Joabu si wipe, Ki Oluwa ki o mu awọn enia rẹ pọ̀ si i ni igba ọgọrun jù bi wọn ti wà: ọba, oluwa mi, gbogbo wọn kì iha ṣe iranṣẹ oluwa mi? ẽṣe ti oluwa mi fi mbère nkan yi? ẽṣe ti on o fi mu Israeli jẹbi.

4 Ṣugbọn ọ̀rọ ọba bori ti Joabu, nitorina Joabu jade lọ, o si la gbogbo Israeli ja, o si de Jerusalemu.

5 Joabu si fi apapọ iye awọn enia na fun Dafidi. Gbogbo Israeli jasi ẹgbẹrun ẹgbẹrun ati ọke marun enia ti nkọ idà: Juda si jasi ọkẹ mẹtalelogun le ẹgbãrun ọkunrin ti nkọ idà.

6 Ṣugbọn Lefi ati Benjamini ni kò kà pẹlu wọn: nitori ọ̀rọ ọba jẹ irira fun Joabu.

7 Nkan yi si buru loju Ọlọrun; o si kọlù Israeli.

8 Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi ti ṣẹ̀ gidigidi ni ṣiṣe nkan yi: ṣugbọn nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ẹ̀ṣẹ iranṣẹ rẹ kuro; nitoriti mo hùwa wère gidigidi.

9 Oluwa si wi fun Gadi, ariran Dafidi pe,

10 Lọ ki o si wi fun Dafidi pe, Bayi li Oluwa wi, mo fi nkan mẹta lọ̀ ọ: yàn ọkan ninu wọn ki emi ki o le ṣe e si ọ.

11 Bẹ̃ni Gadi tọ Dafidi wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, yan fun ara rẹ,

12 Yala ọdun mẹta iyan, tabi iparun li oṣù mẹta niwaju awọn ọta rẹ, ti idà awọn ọta rẹ nle ọ ba; tabi idà Oluwa, ni ijọ mẹta, ani ajakalẹ àrun ni ilẹ na, ti angeli Oluwa o ma pani ja gbogbo àgbegbe Israeli. Njẹ nisisiyi rò o wò, esi wo ni emi o mu pada tọ̀ ẹniti o ran mi.

13 Dafidi si wi fun Gadi pe, iyọnu nla ba mi: jẹ ki emi ki o ṣubu si ọwọ Oluwa nisisiyi: nitori ãnu rẹ̀ pọ̀; ṣugbọn má jẹ ki emi ṣubu si ọwọ ẹnia.

14 Bẹ̃ li Oluwa ran ajakalẹ arun si Israeli: awọn ti o ṣubu ni Israeli jẹ ẹgbã marundilogoji enia.

15 Ọlọrun si ran angeli kan si Jerusalemu lati run u: bi o si ti nrun u, Oluwa wò, o si kãnu nitori ibi na, o si wi fun angeli na ti nrun u pe; O to, da ọwọ rẹ duro. Angeli Oluwa na si duro nibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi.

16 Dafidi si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri angeli Oluwa na duro lagbedemeji aiye ati ọrun, o ni idà fifayọ lọwọ rẹ̀ ti o si nà sori Jerusalemu. Nigbana ni Dafidi ati awọn àgbagba Israeli, ti o wọ aṣọ ọ̀fọ, da oju wọn bolẹ.

17 Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi kọ́ ha paṣẹ lati kaye awọn enia? ani emi li ẹniti o ṣẹ̀ ti mo si ṣe buburu pãpã; ṣugbọn bi o ṣe ti agutan wọnyi, kini nwọn ṣe? Emi bẹ̀ ọ, Oluwa Ọlọrun mi, jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà li ara mi, ati lara ile baba mi; ṣugbọn ki o máṣe li ara awọn enia rẹ ti a o fi arùn kọlu wọn.

18 Nigbana ni angeli Oluwa na paṣẹ fun Gadi lati sọ fun Dafidi pe, ki Dafidi ki o gòke lọ ki o si tẹ pẹpẹ kan fun Oluwa, ni ilẹ ipaka Ornani, ara Jebusi.

19 Dafidi si gòke lọ nipa ọ̀rọ Gadi, ti o sọ li orukọ Oluwa.

20 Ornani si yipada, o si ri angeli na; ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹrin pẹlu rẹ̀ pa ara wọn mọ́. Njẹ Ornani npa ọka lọwọ.

21 Bi Dafidi si ti de ọdọ Ornani, Ornani si wò, o si ri Dafidi, o si ti ibi ilẹ ipaka rẹ̀ jade, o si wolẹ, o dojubolẹ fun Dafidi.

22 Dafidi si wi fun Ornani pe, Fun mi ni ibi ipaka yi, ki emi ki o le tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa; iwọ o si fi fun mi ni iye owo rẹ̀ pipe; ki a le da ajakalẹ arun duro lọdọ awọn enia.

23 Ornani si wi fun Dafidi pe, Mu u fun ra rẹ, si jẹ ki oluwa mi ọba ki o ṣe eyiti o dara loju rẹ̀: wò o mo fi awọn malu pẹlu fun ẹbọ-ọrẹ-sisun, ati ohun èlo ipaka fun igi, ati ọka fun ọrẹ onjẹ; mo fi gbogbo rẹ̀ fun ọ.

24 Dafidi ọba si wi fun Ornani pe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn emi a rà a ni iye owo rẹ̀ pipe nitõtọ, nitoriti emi kì o mu eyi ti iṣe tirẹ fun Oluwa, bẹ̃ni emi kì o ru ẹbọ-ọrẹ sisun laiṣe inawo.

25 Bẹ̃ni Dafidi fi ẹgbẹta ṣekeli wura nipa iwọn fun Ornani fun ibẹ na.

26 Dafidi si tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa, o si ru ẹbọ ọrẹ-sisun ati ẹbọ ọpẹ, o si kepe Oluwa; on si fi iná da a li ohùn lati ọrun wá lori pẹpẹ ẹbọ-ọrẹ sisun na.

27 Oluwa si paṣẹ fun angeli na; on si tun tẹ ida rẹ̀ bọ inu akọ rẹ̀.

28 Li akokò na nigbati Dafidi ri pe Oluwa ti da on li ohùn ni ibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi, o si rubọ nibẹ.

29 Nitori agọ Oluwa ti Mose pa li aginju, ati pẹpẹ ọrẹ sisun, mbẹ ni ibi giga ni Gibeoni li akokò na.

30 Ṣugbọn Dafidi kò le lọ siwaju rẹ̀ lati bere lọwọ Ọlọrun: nitoriti ẹ̀ru idà angeli Oluwa na ba a.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29