1. Kro 13 YCE

A Gbé Àpótí Majẹmu kúrò ní Kiriati Jearimu

1 DAFIDI si ba awọn olori ogun ẹgbẹgbẹrun ati ọrọrun ati olukuluku olori gbèro.

2 Dafidi si wi fun gbogbo ijọ Israeli pe, Bi o ba dara loju nyin, bi o ba si ti ọwọ Oluwa Ọlọrun wa wá, jẹ ki a ranṣẹ kiri sọdọ awọn arakunrin wa ni ibi gbogbo, ti o kù ni gbogbo ilẹ Israeli, ati pẹlu wọn si alufa ati awọn ọmọ Lefi ti mbẹ ni ilu agbegbe wọn, ki nwọn ki o le ko ara wọn jọ sọdọ wa:

3 Ẹ jẹ ki a si tun mu apoti ẹri Ọlọrun wa wa si ọdọ wa: nitoriti awa kò ṣafẹri rẹ̀ li ọjọ Saulu.

4 Gbogbo ijọ na si wipe, ẹ jẹ ki a ṣe bẹ̃: nitori ti nkan na tọ loju gbogbo enia.

5 Bẹ̃ni Dafidi ko gbogbo Israeli jọ lati odò Egipti ani titi de Hemati, lati mu apoti ẹri Ọlọrun lati Kirjat-jearimu wá.

6 Dafidi si gòke ati gbogbo Israeli si Baala, si Kirjat-jearimu, ti iṣe ti Juda, lati mu apoti ẹ̀ri Ọlọrun Oluwa gòke lati ibẹ wá, ti ngbe arin Kerubimu, nibiti a npe orukọ Ọlọrun.

7 Nwọn si gbé apoti ẹri Ọlọrun ka kẹkẹ́ titun lati inu ile Abinadabu wá, ati Ussa ati Ahio ntọ́ kẹkẹ́ na.

8 Ati Dafidi ati gbogbo Israeli fi gbogbo agbara wọn ṣire niwaju Ọlọrun, pẹlu orin, ati pẹlu duru, ati pẹlu psalteri, ati pẹlu timbreli, ati pẹlu simbali, ati pẹlu ipè.

9 Nigbati nwọn si de ilẹ ipaka Kidroni, Ussa nà ọwọ rẹ̀ lati di apoti ẹri na mu; nitoriti awọn malu kọsẹ.

10 Ibinu Oluwa si ru si Ussa, o si lù, nibẹ li o si kú niwaju Ọlọrun.

11 Dafidi si binu nitori ti Oluwa ké Ussa kuro: nitorina ni a ṣe pè ibẹ na ni Peres-Ussa titi di oni.

12 Dafidi si bẹ̀ru Ọlọrun li ọjọ na wipe, Emi o ha ṣe mu apoti ẹri Ọlọrun wá sọdọ mi?

13 Bẹ̃ni Dafidi kò mu apoti ẹri na bọ̀ si ọdọ ara rẹ̀ si ilu Dafidi, ṣugbọn o gbé e ya si ile Obed-Edomu ara Gitti.

14 Apoti ẹri Ọlọrun si ba awọn ara ile Obed-Edomu gbe ni ile rẹ̀ li oṣu mẹta. Oluwa si bukún ile Obed-Edomu ati ohun gbogbo ti o ni.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29