1. Kro 29 YCE

Àwọn Ẹ̀bùn láti fi Kọ́ Tẹmpili

1 DAFIDI ọba si wi fun gbogbo ijọ enia pe, Solomoni ọmọ mi, on nikan ti Ọlọrun ti yàn, jẹ ọmọde o si rọ̀, iṣẹ na si tobi: nitori ti ãfin na kì iṣe fun enia, ṣugbọn fun Ọlọrun Oluwa.

2 Ati pẹlu gbogbo ipa mi ni mo ti fi pèse silẹ fun ile Ọlọrun mi, wura fun ohun ti wura, ati fadakà fun ti fadakà, ati idẹ fun ti idẹ, irin fun ti irin, ati igi fun ti igi; okuta oniki ti a o tẹ̀ bọ okuta lati fi ṣe ọṣọ, ati okuta oniruru àwọ, ati oniruru okuta iyebiye, ati okuta marbili li ọ̀pọlọpọ.

3 Pẹlupẹlu, nitori ni didùn inu mi si ile Ọlọrun mi, mo fi ohun ini mi, eyinì ni wura ati fadakà, fun ile Ọlọrun mi, jù gbogbo eyi ti mo ti pèse silẹ fun ile mimọ́ na,

4 Ẹgbẹ̃dogun talenti wura, ti wura Ofiri, ati ẹ̃dẹgbarin talenti fadakà didara, lati fi bo ogiri ile na:

5 Wura fun ohun èlo wura, ati fadakà fun ohun èlo fadakà, ati fun oniruru iṣẹ nipa ọwọ awọn ọlọnà. Tani si nfẹ loni lati yà ara rẹ̀ si mimọ fun Oluwa?

6 Nigbana ni awọn olori awọn baba ati awọn ijoye ẹ̀ya Israeli, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun ati ọrọrun, pẹlu awọn ijoye iṣẹ ọba fi tinutinu ṣe iranlọwọ,

7 Nwọn si fi fun iṣẹ ile Ọlọrun, ti wura ẹgbẹ̃dọgbọ̀n talenti ati ẹgbãrun dramu, ati ti fadakà ẹgbãrun talenti, ati ti bàba ẹgbãsan talenti, ati ọkẹ marun talenti irin.

8 Ati awọn ti a ri okuta iyebiye lọdọ wọn fi i sinu iṣura ile Oluwa, nipa ọwọ Jehieli ara Gerṣoni.

9 Awọn enia si yọ̀, nitori nwọn fi tinutinu ṣe iranlọwọ nitori pẹlu ọkàn pipe ni nwọn fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun Oluwa: pẹlupẹlu Dafidi ọba si yọ̀ gidigidi.

Dafidi fi Ìyìn fún Ọlọrun

10 Nitorina Dafidi fi iyìn fun Oluwa li oju gbogbo ijọ: Dafidi si wipe, Olubukún ni Iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli baba wa lai ati lailai!

11 Tirẹ Oluwa ni titobi, ati agbara, ati ogo, ati iṣẹgun, ati ọlá-nla: nitori ohun gbogbo li ọrun ati li aiye tirẹ ni; ijọba ni tirẹ, Oluwa, a si gbé ọ leke li ori fun ohun gbogbo.

12 Ọrọ̀ pẹlu ati ọlá ọdọ rẹ ni ti iwá, iwọ si jọba lori ohun gbogbo; li ọwọ rẹ ni agbara ati ipá wà; ati li ọwọ rẹ ni sisọ ni di nla wà, ati fifi agbara fun ohun gbogbo.

13 Njẹ nisisiyi, Ọlọrun wa, awa dupẹ lọwọ rẹ, a si yìn orukọ ogo rẹ.

14 Ṣugbọn tali emi, ati kili awọn enia mi, ti a fi le ṣe iranlọwọ tinutinu bi iru eyi? nitori ohun gbogbo ọdọ rẹ ni ti wá, ati ninu ohun ọwọ rẹ li awa ti fi fun ọ.

15 Nitori alejo ni awa niwaju rẹ, ati atipo bi gbogbo awọn baba wa: ọjọ wa li aiye dabi ojiji, kò si si ireti.

16 Oluwa Ọlọrun wa, gbogbo ohun ọ̀pọlọpọ yi ti awa ti pèse silẹ lati kọ ile fun ọ fun orukọ rẹ mimọ́, lati ọwọ rẹ wá ni, ati gbogbo rẹ̀ jẹ tirẹ.

17 Emi mọ̀ pẹlu, Ọlọrun mi, pe iwọ ndan ọkàn wò, iwọ si ni inudidún si ododo. Bi o ṣe ti emi, ninu ododo ọkàn mi li emi ti fi tinutinu ṣe iranlọwọ gbogbo nkan wọnyi; ati nisisiyi pẹlu ayọ̀ ni mo ti ri awọn enia rẹ ti o wá nihin, lati fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun ọ.

18 Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki ati Israeli, awọn baba wa, pa eyi mọ́ lailai sinu ete ironu ọkàn awọn enia rẹ, si fi idi ọkàn wọn mulẹ si ọdọ rẹ:

19 Si fi ọkàn pipe fun Solomoni ọmọ mi lati pa ofin rẹ, ẹri rẹ, ati ilana rẹ mọ́, ati lati ṣe ohun gbogbo, ati lati kọ́ ãfin, fun eyi ti mo ti pèse silẹ.

20 Dafidi si sọ fun gbogbo ijọ enia pe, Nisisiyi ẹ fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun nyin. Gbogbo enia si fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, nwọn si tẹ ori wọn ba, nwọn wolẹ fun Oluwa ati ọba.

21 Nwọn si ru ẹbọ si Oluwa, nwọn si ru ẹbọ sisun si Oluwa, li ọjọ keji lẹhin ọjọ na, ẹgbẹrun akọmalu, ẹgbẹrun àgbo, ẹgbẹrun ọdọ-agutan, pẹlu ọrẹ mimu wọn, ati ẹbọ miran li ọ̀pọlọpọ fun gbogbo Israeli:

22 Nwọn si jẹ nwọn si mu niwaju Oluwa li ọjọ na pẹlu ayọ̀ nla. Nwọn si tun fi Solomoni ọmọ Dafidi jọba li ẹ̃keji, a si fi ororo yàn a li ọba, ati Sadoku li alufa.

23 Bẹ̃ni Solomoni joko lori itẹ Oluwa bi ọba ni ipò Dafidi baba rẹ̀, o si pọ̀ si i; gbogbo Israeli si gba tirẹ̀ gbọ́.

24 Ati gbogbo awọn ijoye, ati awọn alagbara, ati pẹlu gbogbo awọn ọmọ Dafidi ọba tẹri wọn ba fun Solomoni ọba.

25 Oluwa si gbé Solomoni ga gidigidi li oju gbogbo Israeli, o si fi ọlá nla ọba fun u bi iru eyi ti kò wà fun ọba kan ṣaju rẹ̀ lori Israeli.

Àkójọpọ̀ Ìjọba Dafidi

26 Dafidi ọmọ Jesse si jọba lori gbogbo Israeli.

27 Akokò ti o si fi jọba lori Israeli jẹ ogoji ọdun; ọdun meje li o jọba ni Hebroni, ati mẹtalelọgbọn li o jọba ni Jerusalemu.

28 On si darugbó, o kú rere, o kún fun ọjọ, ọrọ̀ ati ọlá; Solomoni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

29 Njẹ iṣe Dafidi ọba, ibẹ̀rẹ ati ikẹhin, kiyesi i, a kọ ọ sinu iwe Samueli ariran, ati sinu iwe itan Natani woli, ati sinu iwe itan Gadi ariran.

30 Pẹlu gbogbo jijọba ati ipá rẹ̀, ati ìgba ti o kọja lori rẹ̀, ati lori Israeli, ati lori gbogbo ijọba ilẹ wọnni.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29