1. Kro 27 YCE

Àwọn Ológun ati Ètò Òṣèlú

1 NJẸ awọn ọmọ Israeli nipa iye wọn, eyini ni, awọn olori baba, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati awọn ijoye wọn ti nsìn ọba ni olukuluku ọ̀na li ẹgbẹgbẹ, ti nwọle ti si njade li oṣoṣù ni gbogbo oṣù ọdun, jẹ́ ẹgbã mejila.

2 Lori ẹgbẹ kini ti oṣù kini ni Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

3 Ninu awọn ọmọ Peresi on ni olori fun gbogbo awọn olori ogun ti oṣù ekini.

4 Ati lori ẹgbẹ ti oṣù keji ni Dodai ara Ahohi, ati ẹgbẹ tirẹ̀; Mikloti pẹlu nṣe balogun: ẹgbã mejila li o wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀ pẹlu.

5 Olori ogun kẹta fun oṣù kẹta ni Benaiah ọmọ Jehoiada alufa, olori kan: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

6 Eyini ni Benaiah na, akọni enia, ninu awọn ọgbọ̀n, o si jẹ olori awọn ọgbọ̀n: Amisabadi ọmọ rẹ̀ si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

7 Olori ogun kẹrin fun oṣù kẹrin ni Asaheli arakunrin Joabu, ati Sebadiah ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

8 Olori ogun karun fun oṣù karun ni Ṣamhuti ara Israhi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

9 Olori ogun kẹfa fun oṣù kẹfa ni Ira ọmọ Ikkeṣi ara Tekoi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

10 Olori ogun keje fun oṣù keje ni Heleṣi ara Peloni, ninu awọn ọmọ Efraimu: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

11 Olori ogun kẹjọ fun oṣù kẹjọ ni Sibbekai ara Huṣati ti awọn ara Sarehi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

12 Olori ogun kẹsan fun oṣù kẹsan ni Abieseri ara Anatoti ti awọn ara Benjamini: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

13 Olori ogun kẹwa fun oṣù kẹwa ni Maharai ara Netofa, ti awọn ara Sarehi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

14 Olori ogun kọkanla fun oṣù kọkanla ni Benaiah ara Peratoni, ti awọn ọmọ Efraimu: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

15 Olori ogun kejila fun oṣù kejila ni Heldai ara Netofa, ti Otnieli: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

Ètò Àkóso Àwọn Ẹ̀yà Israẹli

16 Ati lori awọn ẹ̀ya Israeli: ijoye lori awọn ọmọ Reubeni ni Elieseri ọmọ Sikri: lori awọn ọmọ Simeoni, Ṣefatiah ọmọ Maaka:

17 Lori awọn ọmọ Lefi, Haṣabiah ọmọ Kemueli: lori awọn ọmọ Aaroni, Sadoku:

18 Lori Juda, Elihu, ọkan ninu awọn arakunrin Dafidi: lori Issakari, Omri ọmọ Mikaeli:

19 Lori Sebuloni, Iṣmaiah ọmọ Obadiah: lori Naftali, Jerimoti ọmọ Asrieli:

20 Lori awọn ọmọ Efraimu, Hoṣea ọmọ Asasiah: lori àbọ ẹ̀ya Manasse, Joeli ọmọ Pedaiah.

21 Lori àbọ ẹ̀ya Manasse ni Gileadi, Iddo ọmọ Sekariah: lori Benjamini, Jaasieli ọmọ Abneri.

22 Lori Dani, Asareeli ọmọ Jerohamu Awọn wọnyi li olori awọn ẹ̀ya Israeli.

23 Ṣugbọn Dafidi kò ka iye awọn ti o wà lati ogun ọdun ati awọn ti kò to bẹ̃; nitori ti Oluwa ti wipe on o mu Israeli pọ̀ si i bi irawọ oju ọrun.

24 Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ si ikà wọn, ṣugbọn kò kà wọn tan, nitori ibinu ṣubu lu Israeli nitori na; bẹ̃ni a kò fi iye na sinu iwe Kronika ti Dafidi ọba.

25 Lori awọn iṣura ọba ni Asmafeti ọmọ Adieli wà: ati lori iṣura oko, ni ilu, ati ni ileto, ati ninu odi ni Jonatani ọmọ Ussiah wà:

26 Ati lori awọn ti nro oko, lati ma ro ilẹ ni Esri ọmọ Kelubi wà:

27 Ati lori awọn ọgba-àjara ni Ṣimei ara Ramoti wà: lori eso ọgba-àjara fun iṣura ati ọti-waini ni Sabdi ọmọ Ṣifmi wà:

28 Ati lori igi-olifi, ati igi-sikamore ti mbẹ ni pẹ̀tẹlẹ ni Baal-hanani ara Gederi wà; ati lori iṣura ororo ni Joaṣi wà.

29 Ati lori awọn agbo malu ti njẹ̀ ni Ṣaroni ni Ṣitrai ara Ṣaroni wà: ati lori agbo malu ti o wà li afonifoji ni Ṣafati ọmọ Adlai wà:

30 Ati lori ibakasiẹ ni Obili ara Iṣmaeli wà: ati lori abo kẹtẹkẹtẹ ni Jehodaiah ara Meronoti wà:

31 Ati lori agbo agutan ni Jasisi ara Hageri wà. Gbogbo awọn wọnyi ni ijoye ohun ini ti iṣe ti Dafidi ọba.

Àwọn Olùdámọ̀ràn Dafidi Ọba

32 Jonatani ẹgbọn Dafidi pẹlu ni ìgbimọ ọlọgbọ́n enia ati akọwe: ati Jehueli ọmọ Hakmoni wà pẹlu awọn ọmọ ọba.

33 Ahitofeli si jẹ ìgbimọ ọba: ati Huṣai ara Arki ni ọrẹ ọba.

34 Ati lẹhin Ahitofeli ni Jehoiada ọmọ Benaiah, ati Abiatari: Joabu si ni arẹ-balogun ogun ọba.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29