1. Kro 20 YCE

Dafidi Ṣẹgun Raba

1 O SI ṣe lẹhin igbati ọdun yipo, li akokò ti awọn ọba lọ si ogun; Joabu si gbé agbara ogun jade, o si ba ilu awọn ọmọ Ammoni jẹ, nwọn si wá, nwọn si do tì Rabba. Ṣugbọn Dafidi duro ni Jerusalemu. Joabu si kọlù Rabba o si pa a run.

2 Dafidi si gbà ade ọba wọn kuro lori rẹ̀, o si ri i pe o wọ̀n talenti wura kan, okuta iyebiye si wà lara rẹ̀; a si fi de Dafidi li ori: o si kó ikogun pipọpipọ lati inu ilu na wá.

3 O si kó awọn enia ti o wà nibẹ jade wá, o si fi ayùn ati irin mimu ati ãke ké wọn. Aní bayi ni Dafidi ṣe si gbogbo ilu awọn ọmọ Ammoni. Ati Dafidi ati gbogbo awọn enia pada bọ̀ si Jerusalemu.

Bíbá Àwọn Òmìrán Filistini Jagun

4 O si ṣe lẹhin eyi li ogun si de ni Geseri pẹlu awọn ara Filistia; li akokò na ni Sibbekai ara Huṣa pa Sippai, ti inu awọn ọmọ òmiran: a si tẹ ori wọn ba.

5 Ogun si tun wà pẹlu awọn ara Filistia; Elhanani ọmọ Jairi si pa Lahamu arakunrin Goliati ara Gati, igi ọ̀kọ rẹ̀ si dabi ìti awunṣọ.

6 Ogun si tun wà ni Gati, nibiti ọkunrin gigun kan gbe wà, ika ati ọmọ-ẹsẹ ẹniti o jẹ mẹrinlelogun, mẹfa li ọwọ kọkan, ati mẹfa li ẹṣẹ kọkan, a si bi i pẹlu fun òmiran.

7 Ṣugbọn nigbati o pe Israeli ni ija, Jonatani ọmọ Ṣimea arakunrin Dafidi pa a.

8 Awọn wọnyi li a bi fun òmiran ni Gati; nwọn si tipa ọwọ Dafidi ṣubu, ati ipa ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29