1. Kro 5 YCE

Ìran Reubẹni

1 NJẸ awọn ọmọ Reubeni, akọbi Israeli, (nitori on li akọbi; ṣugbọn, bi o ti ṣepe o ba ẹní baba rẹ̀ jẹ, a fi ogun ibi rẹ̀ fun awọn ọmọ Josefu ọmọ Israeli: a kì yio si ka itan-idile na gẹgẹ bi ipò ibi.

2 Nitori Juda bori awọn arakunrin rẹ̀, ati lọdọ rẹ̀ ni alaṣẹ ti jade wá; ṣugbọn ogún ibi jẹ ti Josefu:)

3 Mo ni, awọn ọmọ Rubeni akọbi Israeli ni Hanoku, ati Pallu, Hesroni, ati Karmi.

4 Awọn ọmọ Joeli; Ṣemaiah ọmọ rẹ̀, Gogu ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀,

5 Mika ọmọ rẹ̀, Reaiah ọmọ rẹ̀, Baali ọmọ rẹ̀,

6 Beera ọmọ rẹ̀, ti Tiglat-pilneseri ọba Assiria kò ni ìgbekun lọ; ijoye awọn ọmọ Rubeni ni iṣe.

7 Ati awọn arakunrin rẹ̀ nipa idile wọn, nigbati a nkà itàn-idile iran wọn, Jeieli, ati Sekariah ni olori.

8 Ati Bela ọmọ Asasi, ọmọ Ṣema, ọmọ Joeli, ti ngbe Aroeri, ani titi de Nebo ati Baalmeoni:

9 Ati niha ariwa, o tẹ̀do lọ titi de ati-wọ̀ aginju lati odò Eufrate; nitoriti ẹran ọ̀sin wọn pọ̀ si i ni ilẹ Gileadi.

10 Ati li ọjọ Saulu, nwọn ba awọn ọmọ Hagari jagun, ẹniti o ṣubu nipa ọwọ wọn: nwọn si ngbe inu agọ wọn ni gbogbo ilẹ ariwa Gileadi.

Àwọn Ìran Gadi

11 Ati awọn ọmọ Gadi ngbe ọkánkan wọn, ni ilẹ Baṣani titi de Salka:

12 Joeli olori, ati Ṣafamu àtẹle, ati Jaanai, ati Ṣafati ni Baṣani.

13 Ati awọn arakunrin wọn ti ile awọn baba wọn ni Mikaeli, ati Meṣullamu, ati Ṣeba, ati Jorai, ati Jakani, ati Sia, ati Heberi, meje.

14 Wọnyi li awọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jaroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado, ọmọ Busi;

15 Adi, ọmọ Abdieli, ọmọ Guni, olori ile awọn baba wọn.

16 Nwọn si ngbe Gileadi ni Baṣani, ati ninu awọn ilu rẹ̀, ati ninu gbogbo igberiko Ṣaroni, li àgbegbe wọn.

17 Gbogbo wọnyi li a kà nipa itan-idile, li ọjọ Jotamu ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọba Israeli,

Àwọn ọmọ ogun àwọn ẹ̀yà ìhà ìlà oòrùn

18 Awọn ọmọ Rubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ninu awọn ọkunrin alagbara ti nwọn ngbé asà ati idà, ti nwọn si nfi ọrun tafà, ti nwọn si mòye ogun, jẹ ọkẹ meji enia o le ẹgbẹrinlelogún o di ogoji, ti o jade lọ si ogun na.

19 Nwọn si ba awọn ọmọ Hagari jagun, pẹlu Jeturi, ati Nefiṣi ati Nadabu.

20 A si ràn wọn lọwọ si wọn, a si fi awọn ọmọ Hagari le wọn lọwọ, ati gbogbo awọn ti o wà pẹlu wọn: nitoriti nwọn kepè Ọlọrun li ogun na, on si gbọ́ ẹ̀bẹ wọn: nitoriti nwọn gbẹkẹ wọn le e.

21 Nwọn si kó ẹran ọ̀sin wọn lọ; ibakasiẹ ẹgbãmẹ̃dọgbọ̀n ati àgutan ọkẹ mejila o le ẹgbãrun, ati kẹtẹkẹtẹ ẹgbã, ati enia ọkẹ marun.

22 Nitori ọ̀pọlọpọ li o ṣubu ti a pa, nitori lati ọdọ Ọlọrun li ogun na. Nwọn si joko ni ipò wọn titi di igbà ikolọ si ìgbekun.

Ìdajì Ẹ̀yà Manase tí ń gbé Ìhà Ìlà Oòrùn

23 Awọn ọmọkunrin àbọ ẹ̀ya Manasse joko ni ilẹ na: nwọn bi si i lati Baṣani titi de Baal-hermoni, ati Seniri, ati titi de òke Hermoni.

24 Wọnyi si li awọn olori ile awọn baba wọn, Eferi, ati Iṣi, ati Elieli, ati Asrieli, ati Jeremiah, ati Hodafiah, ati Jahdieli, awọn alagbara akọni ọkunrin, ọkunrin olokiki, ati olori ile awọn baba wọn.

A Kó Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Ìlà Oòrùn Lẹ́rú Lọ

25 Nwọn si ṣẹ̀ si Ọlọrun awọn baba wọn, nwọn si ṣe àgbere tọ awọn ọlọrun enia ilẹ na lẹhin, ti Ọlọrun ti parun ni iwaju wọn.

26 Ọlọrun Israeli rú ẹmi Pulu ọba Assiria soke, ati ẹmi Tiglat-pilneseri ọba Assiria, on si kó wọn lọ, ani awọn ọmọ Rubeni ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, o si kó wọn wá si Hala, ati Habori, ati Hara, ati si odò Goṣani, titi di oni yi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29