1 PẸLUPẸLU Dafidi ati awọn olori ogun yà ninu awọn ọmọkunrin Asafu, ati Hemani, ati Jedutuni, fun ìsin yi, awọn ẹniti o ma fi duru ati psalteri, ati kimbali kọrin: ati iye awọn oniṣẹ gẹgẹ bi ìsin wọn jẹ:
2 Ninu awọn ọmọ Asafu, Sakkuri, ati Josefu, ati Netaniah, ati Asarela, awọn ọmọ Asafu labẹ ọwọ Asafu, ti o kọrin gẹgẹ bi aṣẹ ọba.
3 Ti Jedutuni: awọn ọmọ Jedutuni; Gedaliah, ati Seri, ati Jeṣaiah, Haṣabiah, ati Mattitiah, ati Ṣimei, mẹfa, labẹ ọwọ baba wọn Jedutuni, ẹniti o fi duru kọrin, lati ma dupẹ fun ati lati ma yìn Oluwa.
4 Ti Hemani: awọn ọmọ Hemani; Bukkiah, Mattaniah, Ussieli, Ṣebueli, ati Jerimotu, Hananiah, Hanani, Eliata, Giddalti, ati Romamtieseri, Joṣbekaṣa, Malloti, Hotiri, Mahasiotu:
5 Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Hemani, woli ọba ninu ọ̀rọ Ọlọrun, lati ma gbé iwo na soke. Ọlọrun si fun Hemani li ọmọkunrin mẹrinla ati ọmọbinrin mẹta.
6 Gbogbo awọn wọnyi li o wà labẹ ọwọ baba wọn, fun orin ile Oluwa, pẹlu kimbali, psalteri ati duru, fun ìsin ile Ọlọrun: labẹ ọwọ ọba, ni Asafu, Jedutuni, ati Hemani wà.
7 Bẹ̃ni iye wọn, pẹlu awọn arakunrin wọn ti a kọ́ li orin Oluwa, ani gbogbo awọn ti o moye, jasi ọrinlugba o le mẹjọ.
8 Nwọn si ṣẹ keké fun iṣẹ; gbogbo wọn bakanna bi ti ẹni-kekere bẹ̃ni ti ẹni-nla, ti olukọ bi ti ẹniti a nkọ́.
9 Iṣẹkeké ekini si jade wá fun Asafu si Josefu: ekeji si Gedaliah, ẹniti on pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn ọmọ rẹ̀, jẹ mejila:
10 Ẹkẹta si Sakkuri, awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
11 Ẹkẹrin si Isri, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
12 Ẹkarun si Netaniah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
13 Ẹkẹfa si Bukkiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
14 Ekeje si Jeṣarela, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
15 Ẹkẹjọ si Jeṣaiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
16 Ẹkẹsan si Mattaniah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
17 Ẹkẹwa si Ṣimei, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
18 Ẹkọkanla si Asareeli, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
19 Ekejila si Haṣabiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
20 Ẹkẹtala si Ṣubaeli, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
21 Ẹkẹrinla si Mattitiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
22 Ẹkẹ̃dogun si Jeremoti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
23 Ẹkẹrindilogun si Hananiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
24 Ẹkẹtadilogun si Joṣbekaṣa awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
25 Ekejidilogun si Hanani, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
26 Ẹkọkandilogun si Malloti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
27 Ogun si Eliata, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
28 Ẹkọkanlelogun si Hotiri, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
29 Ekejilelogun si Giddalti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
30 Ẹkẹtalelogun si Mahasioti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
31 Ẹkẹrinlelogun si Romamti-eseri, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila.