1. Kro 15 YCE

Ìmúra láti Gbé Àpótí Majẹmu Pada

1 DAFIDI si kọ́ ile fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, o si pese ipò kan fun apoti ẹri Ọlọrun, o si pa agọ kan fun u.

2 Nigbana ni Dafidi wipe, Ẹnikan kò yẹ lati rù apoti ẹri Ọlọrun bikoṣe awọn ọmọ Lefi; nitori awọn ni Oluwa ti yàn lati ma gbé apoti ẹri Ọlọrun, ati lati ma ṣe iranṣẹ fun u titi lai.

3 Dafidi si ko gbogbo Israeli jọ si Jerusalemu, lati gbé apoti ẹri Oluwa gòke lọ si ipò rẹ̀ ti o ti pese fun u.

4 Dafidi si pè awọn ọmọ Aaroni, ati awọn ọmọ Lefi jọ.

5 Ninu awọn ọmọ Kohati; Urieli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ọgọfa:

6 Ninu awọn ọmọ Merari; Asaiah olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ igba o le ogun:

7 Ninu awọn ọmọ Gerṣomu; Joeli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ãdoje:

8 Ninu awọn ọmọ Elisafani; Ṣemaiah olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ igba.

9 Ninu awọn ọmọ Hebroni; Elieli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ọgọrin:

10 Ninu awọn ọmọ Ussieli; Aminadabu olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ mejilelãdọfa.

11 Dafidi si ranṣẹ pè Sadoku ati Abiatari awọn alufa; ati awọn ọmọ Lefi, Urieli, Asaiah, ati Joeli, Ṣemaiah, ati Elieli, ati Aminadabu;

12 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi: ẹ ya ara nyin si mimọ́, ẹnyin ati awọn arakunrin nyin, ki ẹnyin ki o le gbé apoti ẹri Oluwa Ọlọrun Israeli gòke lọ si ibi ti mo ti pèse fun u.

13 Nitoriti ẹnyin kò rù u li akọṣe, ni Oluwa Ọlọrun wa fi ṣe ẹ̀ya si wa li ara, nitori awa kò wá a bi o ti yẹ.

14 Bẹ̃ li awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi ya ara wọn si mimọ́ lati gbe apoti ẹri Oluwa Ọlọrun Israeli gòke wá.

15 Awọn ọmọ Lefi si rù apoti ẹri Ọlọrun bi Mose ti pa a li aṣẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, nwọn fi ọpa rù u li ejika wọn.

16 Dafidi si wi fun olori awọn ọmọ Lefi pe ki nwọn yàn awọn arakunrin wọn, awọn akọrin pẹlu ohun èlo orin, psalteri ati duru, ati kimbali; ti ndún kikan ti o si nfi ayọ gbé ohùn soke.

17 Bẹ̃ li awọn ọmọ Lefi yan Hemani ọmọ Joeli; ati ninu awọn arakunrin rẹ̀, Asafu ọmọ Berekiah; ati ninu awọn ọmọ Merari arakunrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaiah;

18 Ati pẹlu wọn awọn arakunrin wọn li ọwọ́ keji; Sekariah, Beni, ati Jaasieli, ati Ṣemiramotu, ati Jehieli, ati Unni, Eliabu, ati Benaiah, ati Maaseiah, ati Obed-Edomu, ati Jeieli awọn adena.

19 Awọn akọrin si ni Hemani, Asafu, ati Etani, ti awọn ti kimbali ti ndun kikan;

20 Ati Sekariah, ati Asieli, ati Ṣemiramotu, ati Jelieli, ati Unni, ati Eliabu, ati Maaseiah, ati Benaiah, ti awọn ti psaltiri olohùn òke;

21 Ati Mattitiah, ati Elifeleti, ati Mikneiah, lati fi duru olokun mẹjọ ṣaju orin.

22 Ati Kenaniah, olori awọn ọmọ Lefi ni ọ̀ga orin: on ni nkọni li orin, nitoriti o moye rẹ̀.

23 Ati Berekiah, ati Elkana li awọn adena fun apoti ẹri na.

24 Ati Ṣebaniah, ati Jehoṣafati, ati Netaneeli, ati Amasai, ati Sekariah, ati Benaiah, ati Elieseri, awọn alufa, li o nfun ipè niwaju apoti ẹri Ọlọrun: ati Obed-Edomu, ati Jehiah li awọn adena fun apoti ẹri na.

Gbígbé Àpótí Majẹmu Lọ sí Jerusalẹmu

25 Bẹ̃ni Dafidi ati awọn agbagba Israeli, ati awọn olori ẹgbẹgbẹrun, lọ lati gbe apoti ẹri majẹmu Oluwa jade ti ile Obed-Edomu gòke wá pẹlu ayọ̀.

26 O si ṣe, nigbati Ọlọrun ràn awọn ọmọ Lefi lọwọ ti o rù apoti ẹri majẹmu Oluwa, ni nwọn fi malu meje ati àgbo meje rubọ.

27 Dafidi si wọ̀ aṣọ igunwa ọ̀gbọ daradara, ati gbogbo awọn ọmọ Lefi ti nrù apoti ẹri na, ati awọn akọrin, ati Kenaniah olori orin pẹlu awọn akọrin: efodu ọ̀gbọ si wà lara Dafidi.

28 Bayi ni gbogbo Israeli gbé apoti ẹri majẹmu Oluwa gòke wá pẹlu iho ayọ̀, ati iró fère, ati pẹlu ipè, ati kimbali, psalteri ati duru si ndún kikankikan.

29 O si ṣe bi apoti ẹri majẹmu Oluwa na ti de ilu Dafidi ni Mikali ọmọ Saulu obinrin yọju wode ni fèrese, o ri Dafidi ọba njó, o si nṣire; o si kẹgan rẹ̀ li ọkàn rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29