1. Kro 6 YCE

Ìran Àwọn Olórí Àlùfáàa

1 AWỌN ọmọ Lefi; Gerṣoni, Kohati, ati Merari.

2 Ati awọn Kohati; Amramu, Ishari, ati Hebroni, ati Ussieli.

3 Ati awọn Amramu; Aaroni, ati Mose, ati Miriamu. Awọn ọmọ Aaroni; Nadabu, ati Abihu, Eleasari, ati Itamari.

4 Eleasari bi Finehasi, Finehasi si bi Abiṣua,

5 Abiṣua si bi Bukki, Bukki si bi Ussi,

6 Ussi si bi Serahiah, Serahiah si bi Meraioti,

7 Meraioti bi Amariah, Amariah si bi Ahitubu.

8 Ahitubu si bi Sadoku, Sadoku si bi Ahimaasi,

9 Ahimaasi si bi Asariah, Asariah si bi Johanani,

10 Johanani si bi Asariah (on na li ẹniti nṣiṣẹ alufa ni tempili ti Solomoni kọ́ ni Jerusalemu;)

11 Asariah si bi Amariah, Amariah si bi Ahitubu,

12 Ahitubu si bi Sadoki, Sadoki si bi Ṣallumu,

13 Ṣallumu si bi Hilkiah, Hilkiah si bi Asariah,

14 Asariah si bi Seraiah, Seraiah si bi Jehosadaki,

15 Jehosadaki si lọ si oko ẹrú, nigbati Oluwa kó Juda ati Jerusalemu lọ nipa ọwọ Nebukadnessari.

Àwọn Ìran Lefi Yòókù

16 Awọn ọmọ Lefi; Gersọmu, Kohati, ati Merari.

17 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Gerṣomu, Libni, ati Ṣimei.

18 Awọn ọmọ Kohati ni, Amramu, ati Ishari, ati Hebroni, ati Ussieli.

19 Awọn ọmọ Merari; Mahli ati Muṣi. Wọnyi si ni idile awọn ọmọ Lefi, gẹgẹ bi awọn baba wọn.

20 Ti Gerṣomu; Libni ọmọ rẹ̀, Jahati ọmọ rẹ̀, Simma ọmọ rẹ̀.

21 Joa ọmọ rẹ̀, Iddo ọmọ rẹ̀, Sera ọmọ rẹ̀, Jeaterai ọmọ rẹ̀.

22 Awọn ọmọ Kohati; Amminadabu ọmọ rẹ̀, Kora ọmọ rẹ̀, Assiri ọmọ rẹ̀.

23 Elkana ọmọ rẹ̀, ati Ebiasafu ọmọ rẹ̀, ati Assiri ọmọ rẹ̀,

24 Tahati ọmọ rẹ̀, Urieli ọmọ rẹ̀, Ussiah ọmọ rẹ̀, ati Ṣaulu ọmọ rẹ̀,

25 Ati awọn ọmọ Elkana; Amasai, ati Ahimoti.

26 Niti Elkana: awọn ọmọ Elkana; Sofai ọmọ rẹ̀, ati Nahati ọmọ rẹ̀,

27 Eliabu ọmọ rẹ̀, Jerohamu ọmọ rẹ̀, Elkana ọmọ rẹ̀.

28 Awọn ọmọ Samueli; akọbi Faṣni, ati Abiah.

29 Awọn ọmọ Merari; Mahli, Libni, ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀,

30 Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀, Asaiah ọmọ rẹ̀,

Àwọn Ẹgbẹ́ Akọrin Tẹmpili

31 Wọnyi si ni awọn ti Dafidi yàn ṣe olori iṣẹ orin ni ile Oluwa, lẹhin igbati apoti-ẹ̀ri Oluwa ti ni isimi.

32 Nwọn si nfi orin ṣe isin niwaju ibugbe agọ ajọ, titi Solomoni fi kọ́ ile Oluwa ni Jerusalemu tan: nwọn si duro ti iṣẹ óye wọn gẹgẹ bi ipa wọn.

33 Wọnyi si li awọn ti o duro pẹlu awọn ọmọ wọn. Ninu awọn ọmọ Kohati: Hemani akọrin, ọmọ Joeli, ọmọ Samueli,

34 Ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toha,

35 Ọmọ Sufu, ọmọ Elkana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,

36 Ọmọ Elkana, ọmọ Joeli, ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah,

37 Ọmọ Tahati, ọmọ Assiri, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora,

38 Ọmọ Ishari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israeli.

39 Ati arakunrin rẹ̀ Asafu, ti o duro li ọwọ ọ̀tun rẹ̀, ani Asafu, ọmọ Berakiah, ọmọ Ṣimea,

40 Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah, ọmọ Malkiah.

41 Ọmọ Etni, ọmọ Sera, ọmọ Adaiah,

42 Ọmọ Etani, ọmọ Simma, ọmọ Ṣimei,

43 Ọmọ Jahati, ọmọ Gerṣomu, ọmọ Lefi.

44 Awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Merari duro lọwọ osi: Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi, ọmọ Malluku,

45 Ọmọ Haṣabiah, ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah,

46 Ọmọ Amsi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣameri.

47 Ọmọ Mahli, ọmọ Muṣi ọmọ Merari, ọmọ Lefi,

48 Arakunrin wọn pẹlu, awọn ọmọ Lefi, li a yàn si oniruru iṣẹ gbogbo ti agọ ile Ọlọrun.

Ìran Aaroni

49 Ṣugbọn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ nrubọ lori pẹpẹ ẹbọ sisun, ati lori pẹpẹ turari, a si yàn wọn si gbogbo iṣẹ ibi mimọ́-jùlọ, ati lati ṣe ètutu fun Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Mose, iranṣẹ Ọlọrun, ti pa li aṣẹ.

50 Wọnyi si li awọn ọmọ Aaroni; Eleasari ọmọ rẹ̀, Finehasi ọmọ rẹ̀, Abiṣua ọmọ rẹ̀,

51 Bukki ọmọ rẹ̀, Ussi ọmọ rẹ̀, Serahiah ọmọ rẹ̀,

52 Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀, Ahitubu ọmọ rẹ̀,

53 Sadoku ọmọ rẹ̀, Ahimaasi ọmọ rẹ̀.

Ibi tí àwọn Ọmọ Lefi ń gbé

54 Wọnyi si ni ibùgbe wọn gẹgẹ bi budo wọn li àgbegbe wọn, ti awọn ọmọ Aaroni, ti idile awọn ọmọ Kohati: nitori ti wọn ni ipin ikini.

55 Nwọn si fun wọn ni Hebroni ni ilẹ Juda, ati ìgberiko rẹ̀ yi i kakiri.

56 Ṣugbọn oko ilu na, ati ileto wọn, ni nwọn fun Kalebu ọmọ Jefunne.

57 Nwọn si fi ilu Juda fun awọn ọmọ Aaroni, ani Hebroni, ilu àbo ati Libna pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jattiri, ati Eṣtemoa, pẹlu ìgberiko wọn,

58 Ati Hileni pẹlu ìgberiko rẹ̀, Debiri pẹlu ìgberiko rẹ̀,

59 Ati Aṣani pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bet-ṣemeṣi pẹlu ìgberiko rẹ̀:

60 Ati lati inu ẹ̀ya Benjamini; Geba pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Alemeti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Anatoti pẹlu ìgberiko rẹ̀. Gbogbo ilu wọn ni idile wọn jẹ ilu mẹtala.

61 Ati fun awọn ọmọ Kohati, ti o kù ni idile ẹ̀ya na, li a fi keke fi ilu mẹwa fun, ninu àbọ ẹ̀ya, ani lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse.

62 Ati fun awọn ọmọ Gerṣomu ni idile wọn, lati inu ẹ̀ya Issakari, ati inu ẹ̀ya Aṣeri, ati lati inu ẹ̀ya Naftali, ati lati inu ẹ̀ya Manasse ni Baṣani, ilu mẹtala.

63 Fun awọn ọmọ Merari ni idile wọn li a fi keké fi ilu mejila fun, lati inu ẹ̀ya Reubeni, ati lati inu ẹ̀ya Gadi, ati lati inu ẹ̀ya Sebuluni,

64 Awọn ọmọ Israeli fi ilu wọnyi fun awọn ọmọ Lefi pẹlu ìgberiko wọn.

65 Nwọn si fi keké fi ilu wọnyi ti a da orukọ wọn fun ni lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Juda, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini.

66 Ati iyokù ninu idile awọn ọmọ Kohati ni ilu li àgbegbe wọn lati inu ẹ̀ya Efraimu.

67 Nwọn si fi ninu ilu àbo fun wọn, Ṣekemu li òke Efraimu pẹlu ìgberiko rẹ̀; Geseri pẹlu ìgberiko rẹ̀,

68 Ati Jokneamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bet-horoni pẹlu ìgberiko rẹ̀,

69 Ati Aijaloni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Gatrimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀:

70 Ati lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse; Aneri pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bileamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, fun idile awọn ọmọ Kohati iyokù.

71 Awọn ọmọ Gerṣomu lati inu idile àbọ ẹ̀ya Manasse li a fi Golani ni Baṣani fun pẹlu ìgberiko rẹ̀; ati Aṣtaroti pẹlu ìgberiko rẹ̀,

72 Ati lati inu ẹ̀ya Issakari; Kadeṣi pẹlu ìgberiko rẹ̀; Daberati pẹlu ìgberiko rẹ̀,

73 Ati Ramoti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Anemu pẹlu ìgberiko rẹ̀:

74 Ati lati inu ẹ̀ya Aṣeri; Maṣali pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Abdoni pẹlu ìgberiko rẹ̀.

75 Ati Hakoku pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Rehobu pẹlu ìgberiko rẹ̀:

76 Ati lati inu ẹ̀ya Naftali; Kedeṣi ni Galili pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Hammoni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Kirjataimu pẹlu ìgberiko rẹ̀.

77 Fun iyokù awọn ọmọ Merari li a fi Rimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun, Tabori pẹlu ìgberiko rẹ̀, lati inu ẹ̀ya Sebuluni:

78 Ati li apa keji Jordani leti Jeriko, ni iha ariwa Jordani, li a fi Beseri li aginju pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jasa pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun wọn, lati inu ẹ̀ya Rubeni,

79 Ati Kedemoti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Mefaati pẹlu ìgberiko rẹ̀:

80 Ati lati inu ẹ̀ya Gadi, Ramoti ni Gileadi pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Mahanaimu pẹlu ìgberiko rẹ̀.

81 Ati Heṣboni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jaseri pẹlu ìgberiko rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29