1. Kro 9 YCE

Àwọn tí wọ́n dé láti Oko Ẹrú Babilonii

1 A si ka iye gbogbo Israeli ni idile idile wọn; si kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli: Juda li a si kó lọ si Babiloni nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

2 Awọn ti o tetekọ gbe ilẹ ini wọn, ati ilu wọn li awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi ati awọn Netinimu.

3 Ni Jerusalemu ni, ninu awọn ọmọ Juda, ati ninu awọn ọmọ Benjamini, ati ninu awọn ọmọ Efraimu, ati Manasse ngbe;

4 Utai ọmọ Ammihudi, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ninu awọn ọmọ Faresi ọmọ Juda.

5 Ati ninu awọn ara Ṣilo, Asaiah akọbi, ati awọn ọmọ rẹ̀.

6 Ati ninu awọn ọmọ Sera, Jegueli, ati awọn arakunrin wọn, ẹdẹgbẹrin o di mẹwa.

7 Ati ninu awọn ọmọ Benjamini; Sallu, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah, ọmọ Senua.

8 Ati Ibneiah ọmọ Jerohamu, ati Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri, ati Meṣullamu ọmọ Ṣefatiah, ọmọ Regueli, ọmọ Ibniah;

9 Ati awọn arakunrin wọn, gẹgẹ bi idile wọn ẹgbẹrun o din mẹrinlelogoji. Gbogbo awọn ọkunrin wọnyi ni olori ninu awọn baba ni ile baba wọn.

Àwọn Àlùfáàa tí wọn ń gbé Jerusalẹmu

10 Ati ninu awọn alufa; Jedaiah, ati Jehoiaribu ati Jakini,

11 Ati Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu olori ile Ọlọrun;

12 Ati Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkijah, ati Maasai ọmọ Adieli, ọmọ Jasera, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Meṣillemiti, ọmọ Immeri;

13 Ati awọn arakunrin wọn olori ile baba wọn, ẹgbẹsan o din ogoji; awọn alagbara akọni ọkunrin fun iṣẹ ìsin ile Ọlọrun.

Àwọn Ọmọ Lefi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu

14 Ati ninu awọn ọmọ Lefi; Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah, ninu awọn ọmọ Merari;

15 Ati Bakbakkari, Hereṣi, ati Galali, ati Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu;

16 Ati Obadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni, ati Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkanah, ti ngbe ileto awọn ara Netofa.

Àwọn Aṣọ́nà Tẹmpili tí wọn ń gbé Jerusalẹmu

17 Awọn adena si ni Ṣallumu, ati Akkubu, ati Talmoni, ati Ahimani, ati awọn arakunrin wọn; Ṣallumu li olori;

18 Titi di isisiyi awọn ti o duro li oju-ọ̀na ọba niha ilà-õrùn; adena ni wọn li ẹgbẹ awọn ọmọ Lefi.

19 Ati Ṣallumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora, ati awọn arakunrin rẹ̀, ti ile baba rẹ̀, awọn ọmọ Kora, ni mbẹ lori iṣẹ ìsin na, olutọju iloro agọ na; awọn baba wọn ti mbẹ lori ibudo Oluwa ti nwọn ima ṣọ atiwọ̀le na.

20 Ati Finehasi ọmọ Eleasari ni olori lori wọn ni igba atijọ, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.

21 Sekariah ọmọ Meṣelemiah ni adena ilẹkun agọ ajọ enia.

22 Gbogbo wọnyi ti a ti yàn lati ṣe adena loju iloro, jẹ igba o le mejila. A ka awọn wọnyi nipa idile wọn ni ileto wọn, awọn ẹniti Dafidi ati Samueli, ariran, ti yàn nitori otitọ wọn.

23 Bẹ̃li awọn wọnyi ati awọn ọmọ wọn nṣẹ abojuto iloro ile Oluwa, eyini ni ile agọ na fun iṣọ.

24 Ni igun mẹrẹrin ni awọn adena mbẹ, niha ilà-õrùn, ìwọ-õrún, ariwa ati gusu.

25 Ati awọn arakunrin wọn ngbe ileto wọn, lati ma wá pẹlu wọn ni ijọ ekeje lati igba de igba.

26 Nitoriti awọn ọmọ Lefi wọnyi jẹ awọn olori adena mẹrin, nwọn si wà ninu iṣẹ na, nwọn si wà lori iyara ati ibi iṣura ile Ọlọrun.

27 Nwọn a si ma sùn yi ile Ọlọrun ka, nitori ti nwọn ni itọju na, ati ṣiṣi rẹ̀ li orowurọ jẹ ti wọn.

Àwọn Ọmọ Lefi Yòókù

28 Ati awọn kan ninu wọn ni itọju ohun elo ìsin, lati ma kó wọn sinu ile ati si ode ni iye.

29 Ninu wọn li a yàn lati ma bojuto ohun elo, ati gbogbo ohun elo ibi mimọ́, ati iyẹfun kikunna, ati ọti-waini, ati ororo, ati ojia, ati turari.

30 Ati omiran ninu awọn ọmọ awọn alufa si fi turari ṣe ororo.

31 Ati Mattitiah, ọkan ninu awọn ọmọ Lefi, ti iṣe akọbi Ṣallumu ọmọ Kora, li o nṣe alabojuto iṣẹ ohun ti a ndín.

32 Ati ninu awọn arakunrin wọn ninu awọn ọmọ Kohati li o nṣe itọju akara-ifihan, lati mã pese rẹ̀ li ọjọjọ isimi.

33 Wọnyi si li awọn akọrin, olori awọn baba awọn ọmọ Lefi, nwọn kò ni iṣẹ ninu iyara wọnni; nitori ti nwọn wà lẹnu iṣẹ wọn lọsan ati loru.

34 Awọn wọnyi ni olori baba awọn ọmọ Lefi, ni iran wọn, olori ni nwọn: awọn wọnyi ni ngbe Jerusalemu.

Àwọn Baba Ńlá ati Àwọn Àtìrandíran Saulu Ọba

35 Ati ni Gibeoni ni baba Gibeoni ngbe, Jegieli, orukọ aya ẹniti ijẹ Maaka.

36 Akọbi ọmọ rẹ̀ si ni Abdoni, ati Suri ati Kiṣi, ati Baali, ati Neri, ati Nadabu,

37 Ati Gedori, ati Ahio, ati Sekariah ati Mikloti.

38 Mikloti si bi Ṣimeamu. Awọn wọnyi si mba awọn arakunrin wọn gbe ni Jerusalemu, kọju si awọn arakunrin wọn.

39 Neri si bi Kiṣi, Kiṣi si bi Saulu, Saulu si bi Jonatani, ati Malkiṣua, ati Abinadabu, ati Eṣbaali.

40 Ati ọmọ Jonatani ni Merib-baali; Merib-baali si bi Mika.

41 Ati awọn ọmọ Mika ni Pitoni, ati Meleki, ati Tarea, ati Ahasi.

42 Ahasi si bi Jara; Jara si bi Alemeti, ati Asmafeti, ati Simri, Simri si bi Mosa,

43 Mosa si bi Binea, ati Refaiah ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀, Aseli ọmọ rẹ̀.

44 Aseli si bi ọmọ mẹfa, orukọ wọn ni wọnyi; Asrikamu, Bokeru, ati Iṣmaeli, ati Ṣeariah, ati Obadiah ati Hanani. Wọnyi li awọn ọmọ Aseli.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29